Efe 2:3-9
Efe 2:3-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ninu awọn ẹniti gbogbo wa pẹlu ti wà rí ninu ifẹkufẹ ara wa, a nmu ifẹ ara ati ti inu ṣẹ; ati nipa ẹda awa si ti jẹ ọmọ ibinu, gẹgẹ bi awọn iyoku pẹlu. Ṣugbọn Ọlọrun, ẹniti iṣe ọlọrọ̀ li ãnu, nitori ifẹ nla rẹ̀ ti o fi fẹ wa, Nigbati awa tilẹ ti kú nitori irekọja wa, o sọ wa di ãye pẹlu Kristi (ore-ọfẹ li a ti fi gba nyin là). O si ti ji wa dide pẹlu rẹ̀, o si ti mu wa wa joko pẹlu rẹ̀ ninu awọn ọrun ninu Kristi Jesu: Pe ni gbogbo ìgba ti mbọ ki o ba le fi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀ ti o pọ rekọja han ninu iṣeun rẹ̀ si wa ninu Kristi Jesu. Nitori ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ́; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikaranyin: ẹ̀bun Ọlọrun ni: Kì iṣe nipa iṣẹ, ki ẹnikẹni má bã ṣogo.
Efe 2:3-9 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo àwa yìí náà ti wà lára irú wọn rí, nígbà tí à ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, tí à ń ṣe àwọn nǹkan tí ara bá fẹ́ ati àwọn ohun tí ọkàn bá ti rò. Nígbà náà, nípa ti ẹ̀dá ara, àwa náà wà ninu àwọn ọmọ tí Ọlọrun ìbá bínú sí, gẹ́gẹ́ bí àwọn eniyan yòókù. Ṣugbọn nítorí ìfẹ́ ńlá tí Ọlọrun tí ó ní àánú pupọ ní sí wa, ó sọ wá di alààyè pẹlu Kristi nígbà tí a ti di òkú ninu ìwàkíwà wa. Oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là. Ọlọrun tún jí wa dìde pẹlu Kristi Jesu, ó wá fi wá jókòó pẹlu rẹ̀ lọ́run, kí ó lè fihàn ní àkókò tí ó ń bọ̀ bí ọlá oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ti tóbi tó, nípa àánú tí ó ní sí wa ninu Kristi Jesu. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là nípa igbagbọ. Kì í ṣe nítorí iṣẹ́, ẹ̀bùn Ọlọrun ni. Kì í ṣe ìtorí iṣẹ́ tí eniyan ṣe, kí ẹnikẹ́ni má baà máa gbéraga.
Efe 2:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ, àti nípa ìṣẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìyókù pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa, nígbà tí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékọjá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi, oore-ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là. Ọlọ́run sì ti jí wa dìde pẹ̀lú Kristi, ó sì ti mú wa jókòó pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run nínú Kristi Jesu. Pé ni gbogbo ìgbà tí ń bọ̀ kí ó bà á lè fi ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí o pọ̀ rékọjá hàn fún wa nínú ìṣeun rẹ̀ sì wà nínú Kristi Jesu. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́. Èyí kì í ṣe nípa agbára ẹ̀yin fúnrayín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni: Kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo.