Efe 1:7-12
Efe 1:7-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rẹ̀, idariji ẹ̀ṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀; Eyiti o sọ di pupọ fun wa ninu gbogbo ọgbọ́n ati oye, Ẹniti o ti sọ ohun ijinlẹ ifẹ rẹ̀ di mimọ̀ fun wa, gẹgẹ bi idunnú rẹ̀, eyiti o ti pinnu ninu rẹ̀, Fun iṣẹ iriju ti kikun akoko na, ki o le ko ohun gbogbo jọ ninu Kristi, iba ṣe eyiti mbẹ ninu awọn ọrun, tabi eyiti mbẹ li aiye, ani ninu rẹ̀: Ninu ẹniti a fi wa ṣe ini rẹ̀ pẹlu, awa ti a ti yan tẹlẹ, gẹgẹ bi ipinnu ẹniti nṣiṣẹ ohun gbogbo gẹgẹ bi ìmọ ifẹ rẹ̀: Ki awa ki o le jẹ fun iyin ogo rẹ̀, awa ti a ti ni ireti ṣaju ninu Kristi
Efe 1:7-12 Yoruba Bible (YCE)
Nípasẹ̀ Kristi ni a ti ní ìdáǹdè nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti rí ìdáríjì gbà fún àwọn ìrékọjá wa, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. A ní oore-ọ̀fẹ́ yìí lọpọlọpọ! Ó fún wa ní gbogbo ọgbọ́n ati òye. Ó jẹ́ kí á mọ àṣírí ìfẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ètò tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ tí ó ti ṣe ninu Kristi. Èyí ni pé, nígbà tí àkókò bá tó, kí ó lè ṣe ohun gbogbo ní àṣeparí ninu Kristi nígbà tí ó bá yá, ìbáà ṣe àwọn ohun tí ó wà ninu àwọn ọ̀run, tabi àwọn ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, kí ó lè sọ wọ́n di ọ̀kan ninu Kristi. Nípasẹ̀ Kristi kan náà ni Ọlọrun ti pín wa ní ogún. Ètò tí ó ti ṣe fún wa nìyí, òun tí ó ń mú ohun gbogbo ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀. Àyọrísí gbogbo èyí ni pé kí àwa Juu tí a kọ́kọ́ ní ìrètí ninu Kristi lè yìn ín lógo.
Efe 1:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye, Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi, èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi. Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀, kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi.