Efe 1:17-18
Efe 1:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Pe ki Ọlọrun Jesu Kristi Oluwa wa, Baba ogo, le fun nyin li Ẹmi nipa ti ọgbọ́n ati ti ifihan ninu ìmọ rẹ̀: Ki oju ọkàn nyin le mọlẹ; ki ẹnyin ki o le mọ ohun ti ireti ìpe rẹ̀ jẹ, ati ohun ti ọrọ̀ ogo ini rẹ̀ ninu awọn enia mimọ́ jẹ
Efe 1:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Mò ń gbadura pé kí Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba ológo, lè fun yín ní ẹ̀mí ọgbọ́n, kí ó sì jẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀ tí ó kún nípa òun alára. Mo sì tún ń gbadura pé kí ó lè là yín lójú ẹ̀mí, kí ẹ lè mọ ìrètí tí ó ní tí ó fi pè yín, kí ẹ sì lè mọ ògo tí ó wà ninu ogún rẹ̀ tí yóo pín fun yín pẹlu àwọn onigbagbọ
Efe 1:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́