Efe 1:13-14
Efe 1:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ninu ẹniti, ẹnyin pẹlu, nigbati ẹnyin ti gbọ ọrọ otitọ nì, ihinrere igbala nyin, ninu ẹniti nigbati ẹnyin ti gbagbọ pẹlu, a fi Ẹmi Mimọ́ ileri nì ṣe edidi nyin, Eyiti iṣe ẹri ini wa, fun irapada ohun ini Ọlọrun si iyìn ogo rẹ̀.
Efe 1:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Ninu Kristi kan náà ni ẹ̀yin tí kì í ṣe Juu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́, tíí ṣe ìyìn rere ìgbàlà yín tí ẹ gbàgbọ́. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni Ọlọrun ti fi Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ṣe ìlérí fun yín bí èdìdì. Ẹ̀mí Mímọ́ yìí jẹ́ onídùúró ogún tí a óo gbà nígbà tí Ọlọrun bá dá àwọn eniyan rẹ̀ nídè, kí á lè yin Ọlọrun lógo.
Efe 1:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìhìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀, èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.