Oni 9:1-12

Oni 9:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)

NITORI nkan yi ni mo rò li aiya mi, ani lati wadi gbogbo eyi pe, olododo, ati ọlọgbọ́n, ati iṣẹ wọn, lọwọ Ọlọrun li o wà: ifẹni ati irira, kò si ẹniti o mọ̀, gbogbo eyi wà niwaju wọn. Bakanna li ohun gbogbo ri fun gbogbo wọn: ohun kanna li o nṣe si olododo, ati si ẹni buburu; si enia rere, ati si mimọ́ ati si alaimọ́; si ẹniti nrubọ, ati si ẹniti kò rubọ: bi enia rere ti ri, bẹ̃ li ẹ̀lẹṣẹ; ati ẹniti mbura bi ẹniti o bẹ̀ru ibura. Eyi ni ibi ninu ohun gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn, pe iṣẹ kanna ni si gbogbo wọn: ati pẹlu, aiya awọn ọmọ enia kún fun ibi, isinwin mbẹ ninu wọn nigbati wọn wà lãye, ati lẹhin eyini; nwọn a lọ sọdọ awọn okú. Nitoripe tali ẹniti a yàn, ti ireti alãye wà fun: nitoripe ãye ajá san jù okú kiniun lọ. Nitori alãye mọ̀ pe awọn o kú; ṣugbọn awọn okú kò mọ̀ ohun kan, bẹ̃ni nwọn kì ili ère mọ; nitori iranti wọn ti di igbagbe. Ifẹ wọn pẹlu, ati irira wọn, ati ilara wọn, o parun nisisiyi; bẹ̃ni nwọn kò si ni ipin mọ lailai ninu ohun gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn. Ma ba tirẹ lọ, ma fi ayọ̀ jẹ onjẹ rẹ, ki o si mã fi inu-didun mu ọti-waini rẹ: nitoripe Ọlọrun tẹwọgba iṣẹ rẹ nisisiyi. Jẹ ki aṣọ rẹ ki o ma fún nigbagbogbo; ki o má si jẹ ki ori rẹ ki o ṣe alaini ororo ikunra, Ma fi ayọ̀ ba aya rẹ gbe ti iwọ fẹ ni gbogbo ọjọ aiye asan rẹ, ti o fi fun ọ labẹ õrùn ni gbogbo ọjọ asan rẹ: nitori eyini ni ipin tirẹ li aiye yi, ati ninu lãla ti iwọ ṣe labẹ õrùn. Ohunkohun ti ọwọ rẹ ri ni ṣiṣe, fi agbara rẹ ṣe e; nitoriti kò si ete, bẹ̃ni kò si ìmọ, tabi ọgbọ́n, ni isa-okú nibiti iwọ nrè. Mo pada, mo si ri labẹ õrùn, pe ire-ije kì iṣe ti ẹniti o yara, bẹ̃li ogun kì iṣe ti alagbara, bẹ̃li onjẹ kì iṣe ti ọlọgbọ́n, bẹ̃li ọrọ̀ kì iṣe ti ẹni oye, bẹ̃li ojurere kì iṣe ti ọlọgbọ́n-inu; ṣugbọn ìgba ati eṣe nṣe si gbogbo wọn. Nitoripe enia pẹlu kò mọ̀ ìgba tirẹ̀; bi ẹja ti a mu ninu àwọn buburu, ati bi ẹiyẹ ti a mu ninu okùn; bẹ̃li a ndẹ awọn ọmọ enia ni ìgba buburu, nigbati o ṣubu lù wọn lojiji.

Oni 9:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo fi sọ́kàn. Mo yẹ gbogbo rẹ̀ wò, bí ó ti jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn olódodo, àwọn ọlọ́gbọ́n, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn wà. Bí ti ìfẹ́ ni, bí ti ìkórìíra ni, ẹnìkan kò mọ̀. Asán ni gbogbo ohun tí ó wà níwájú wọn. Nítorí nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn: ati olódodo ati ẹlẹ́ṣẹ̀, ati eniyan rere ati eniyan burúkú, ati ẹni mímọ́, ati ẹni tí kò mọ́, ati ẹni tí ń rúbọ ati ẹni tí kì í rú. Bí eniyan rere ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹlẹ́ṣẹ̀ náà rí. Bákan náà ni ẹni tí ń búra ati ẹni tí ó takété sì ìbúra. Nǹkankan tí ó burú, ninu àwọn nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé ni pé, ìpín kan náà ni gbogbo ọmọ aráyé ní, ọkàn gbogbo eniyan kún fún ibi, ìwà wèrè sì wà lọ́kàn wọn; lẹ́yìn náà, wọn a sì kú. Ṣugbọn ìrètí ń bẹ fún ẹni tí ó wà láàyè, nítorí pé ààyè ajá wúlò ju òkú kinniun lọ. Nítorí alààyè mọ̀ pé òun óo kú, ṣugbọn òkú kò mọ nǹkankan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní èrè kan mọ́, a kò sì ní ranti wọn mọ́. Ìfẹ́, ati ìkórìíra, ati ìlara wọn ti parun, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ laelae ninu ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé. Máa lọ fi tayọ̀tayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ, sì máa mu ọtí waini rẹ pẹlu ìdùnnú, nítorí Ọlọrun ti fi ọwọ́ sí ohun tí ò ń ṣe. Máa wọ aṣọ àríyá nígbà gbogbo, sì máa fi òróró pa irun rẹ dáradára. Máa gbádùn ayé pẹlu aya rẹ, olólùfẹ́ rẹ, ní gbogbo ọjọ́ asán tí Ọlọrun fún ọ nílé ayé. Nítorí ìpín tìrẹ nìyí láyé ninu làálàá tí ò ń ṣe. Ohunkohun tí o bá ti dáwọ́ lé, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é nítorí, kò sí iṣẹ́, tabi èrò, tabi ìmọ̀, tabi ọgbọ́n, ní isà òkú tí ò ń lọ. Bákan náà, mo rí i pé, láyé, ẹni tí ó yára, tí ó lè sáré, lè má borí ninu eré ìje, alágbára lè jagun kó má ṣẹgun, ọlọ́gbọ́n lè má rí oúnjẹ jẹ, eniyan lè gbọ́n kó lóye, ṣugbọn kí ó má lówó lọ́wọ́, ẹni tí ó mọ iṣẹ́ ṣe sì lè má ní ìgbéga, àjálù ati èèṣì lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni. Kò sí ẹni tí ó mọ àkókò tirẹ̀. Bíi kí ẹja kó sinu àwọ̀n burúkú, tabi kí ẹyẹ kó sinu pańpẹ́, ni tàkúté ibi ṣe máa ń mú eniyan, nígbà tí àkókò ibi bá dé bá wọn.

Oni 9:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olóòtọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bóyá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun. Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn yàn—olóòtọ́ àti ènìyàn búburú, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rú ẹbọ àti àwọn tí kò rú ẹbọ. Bí ó ti rí pẹ̀lú ènìyàn rere bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúra bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra. Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú. Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ! Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan wọn kò ní èrè kankan mọ́, àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé. Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn àti ìlara wọn ti parẹ́: láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run ṣíjú àánú wo ohun tí o ṣe. Máa wọ aṣọ funfun nígbàkúgbà kí o sì máa fi òróró yan orí rẹ nígbà gbogbo. Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn. Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ. Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùn Eré ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yára tàbí ogun fún alágbára bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́n tàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òye tàbí ojúrere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀; ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn. Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé: Gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburú tàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùn gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibi tí ó ṣubú lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa