Oni 8:1-17

Oni 8:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

TALI o dabi ọlọgbọ́n enia? tali o si mọ̀ itumọ nkan? Ọgbọ́n enia mu oju rẹ̀ dán, ati igboju rẹ̀ li a o si yipada. Mo ba ọ mọ̀ ọ pe, ki iwọ ki o pa ofin ọba mọ́, eyini si ni nitori ibura Ọlọrun. Máṣe yara ati jade kuro niwaju rẹ̀: máṣe duro ninu ohun buburu; nitori ohun ti o wù u ni iṣe. Nibiti ọ̀rọ ọba gbe wà, agbara mbẹ nibẹ; tali o si le wi fun u pe, kini iwọ nṣe nì? Ẹnikẹni ti o pa ofin mọ́ kì yio mọ̀ ohun buburu: aiya ọlọgbọ́n enia si mọ̀ ìgba ati àṣa. Nitoripe ohun gbogbo ti o wuni ni ìgba ati àṣa wà fun, nitorina òṣi enia pọ̀ si ori ara rẹ̀. Nitoriti kò mọ̀ ohun ti mbọ̀: tali o si le wi fun u bi yio ti ri? Kò si enia kan ti o lagbara lori ẹmi lati da ẹmi duro; bẹ̃ni kò si lagbara li ọjọ ikú: kò si iránpada ninu ogun na; bẹ̃ni ìwa buburu kò le gbà awọn oluwa rẹ̀. Gbogbo nkan wọnyi ni mo ri, mo si fiyè si iṣẹ gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn: ìgba kan mbẹ ninu eyi ti ẹnikan nṣe olori ẹnikeji fun ifarapa rẹ̀. Bẹ̃ni mo si ri isinkú enia buburu, ati awọn ti o ṣe otitọ ti o wá ti o si lọ kuro ni ibi mimọ́, a si gbagbe wọn ni ilu na: asan li eyi pẹlu. Nitoriti a kò mu idajọ ṣẹ kánkán si iṣẹ buburu, nitorina aiya awọn ọmọ enia mura pãpa lati huwa ibi. Bi ẹlẹṣẹ tilẹ ṣe ibi nigba ọgọrun, ti ọjọ rẹ̀ si gùn, ṣugbọn nitõtọ, emi mọ̀ pe yio dara fun awọn ti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o bẹ̀ru niwaju rẹ̀: Ṣugbọn kì yio dara fun enia buburu, bẹ̃ni kì yio fa ọjọ rẹ̀ gun ti o dabi ojiji, nitoriti kò bẹ̀ru niwaju Ọlọrun. Asan kan mbẹ ti a nṣe li aiye; niti pe, olõtọ enia wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ buburu; ati pẹlu, enia buburu wà, awọn ti o nri fun bi iṣẹ olododo: mo ni asan li eyi pẹlu. Nigbana ni mo yìn iré, nitori enia kò ni ohun rere labẹ õrùn jù jijẹ ati mimu, ati ṣiṣe ariya: nitori eyini ni yio ba a duro ninu lãla rẹ̀ li ọjọ aiye rẹ̀, ti Ọlọrun fi fun u labẹ õrùn. Nigbati mo fi aiya mi si ati mọ̀ ọgbọ́n, on ati ri ohun ti a ṣe lori ilẹ: (ẹnikan sa wà pẹlu ti kò fi oju rẹ̀ ba orun li ọsan ati li oru.) Nigbana ni mo wò gbogbo iṣẹ Ọlọrun, pe enia kò le ridi iṣẹ ti a nṣe labẹ õrùn: nitoripe bi enia tilẹ gbiyanju ati wadi rẹ̀, sibẹ kì yio le ri i; ati pẹlupẹlu bi ọlọgbọ́n enia rò lati wadi rẹ̀, sibẹ kì yio lè ridi rẹ̀.

Oni 8:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Ta ló dàbí ọlọ́gbọ́n? Ta ló sì mọ ìtumọ̀ nǹkan? Ọgbọ́n ní ń mú kí ojú ọlọ́gbọ́n máa dán, á mú kí ó tújúká kí ó gbàgbé ìṣòro. Pa òfin ọba mọ́, má sì fi ìwàǹwára jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọrun. Tètè kúrò níwájú ọba, má sì pẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá ń di ibinu, nítorí pé ohun tí ó bá wù ú ló lè ṣe. Nítorí pé ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé. Bí ọba bá ṣe nǹkan, ta ló tó yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wò? Ẹni tí ó bá ń pa òfin mọ́ kò ní rí ibi; ọlọ́gbọ́n mọ àkókò ati ọ̀nà tí ó yẹ láti gbà ṣe nǹkan. Gbogbo nǹkan ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wahala wọ ẹ̀dá lọ́rùn. Ẹnikẹ́ni kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la; ta ló lè sọ fún eniyan bí yóo ṣe ṣẹlẹ̀? Kò sí ẹni tí ó lágbára láti dá ẹ̀mí dúró, tabi láti yí ọjọ́ ikú pada, gbèsè ni ikú, kò sí ẹni tí kò ní san án; ìwà ibi àwọn tí ń ṣe ibi kò sì le gbà wọ́n sílẹ̀. Nígbà tí mo fi tọkàntọkàn pinnu láti ṣàkíyèsí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé, mo rí i pé ọpọlọpọ eniyan ní ń lo agbára wọn lórí àwọn ẹlòmíràn sí ìpalára ara wọn. Mo rí àwọn ẹni ibi tí a sin sí ibojì. Nígbà ayé wọn, wọn a ti máa ṣe wọlé-wọ̀de ní ibi mímọ́, àwọn eniyan a sì máa yìn wọ́n, ní ìlú tí wọn tí ń ṣe ibi. Asán ni èyí pẹlu. Nítorí pé wọn kì í tètè dá ẹjọ́ àwọn ẹni ibi, ni ọkàn ọmọ eniyan fi kún fún ìwà ibi. Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tilẹ̀ ṣe ibi ní ọpọlọpọ ìgbà tí ọjọ́ rẹ̀ sì gùn, sibẹsibẹ mo mọ̀ pé yóo dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọrun. Ṣugbọn kò ní dára fún ẹni ibi, bẹ́ẹ̀ sì ni ọjọ́ rẹ̀ kò ní gùn bí òjìji, nítorí kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ohun asán kan tún wà tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé yìí, a rí àwọn olódodo tí wọn ń jẹ ìyà àwọn eniyan burúkú, tí eniyan burúkú sì ń gba èrè olódodo, asán ni èyí pẹlu. Ìmọ̀ràn mi ni pé, kí eniyan máa gbádùn, nítorí kò sí ire kan tí ọmọ eniyan tún ń ṣe láyé ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lọ; nítorí èyí ni yóo máa bá a lọ ní gbogbo ọjọ́ tí Ọlọrun fún un láyé. Nígbà tí mo fi tọkàntọkàn pinnu láti wá ọgbọ́n ati láti wo iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní ayé, bí eniyan kì í tíí fi ojú ba oorun tọ̀sán-tòru, mo wá rí gbogbo iṣẹ́ Ọlọrun pé, kò sí ẹni tí ó lè rí ìdí iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé. Kò sí bí eniyan ti lè ṣe làálàá tó, kò lè rí ìdí rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ń sọ pé àwọn mọ iṣẹ́ OLUWA, sibẹsibẹ wọn kò lè rí ìdí rẹ̀.

Oni 8:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ta ni ó dàbí ọlọ́gbọ́n ènìyàn? Ta ni ó mọ ìtumọ̀ ohun gbogbo? Ọgbọ́n a máa mú ojú ènìyàn dán ó sì máa ń pààrọ̀ ìrínisí rẹ̀. Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run. Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró nínú ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn. Níwọ́n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è sọ fún un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?” Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò ní wá sí ìpalára kankan, àyà ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò sì mọ àsìkò tí ó tọ́ àti ọ̀nà tí yóò gbà ṣe é. Ohun gbogbo ni ó ní àsìkò àti ọ̀nà tí ó tọ́ láti ṣe, ṣùgbọ́n, òsì ènìyàn pọ̀ sí orí ara rẹ̀. Níwọ́n ìgbà tí kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́-ọ̀lá, ta ni ó le è sọ fún un ohun tí ó ń bọ̀? Kò sí ẹni tí ó lágbára lórí afẹ́fẹ́ láti gbà á dúró nítorí náà, kò sí ẹni tí ó ní agbára lórí ọjọ́ ikú rẹ̀. Bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìkà kò ní fi àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀; bí ó ti jẹ́ wí pé kò sí ẹni tí a dá sílẹ̀ nígbà ogun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà búburú kò le gba àwọn tí ó ń ṣe é sílẹ̀. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń múlò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kan wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tókù fún ìpalára rẹ̀. Nígbà náà ni mo tún rí ìsìnkú ènìyàn búburú—àwọn tí wọ́n máa ń wá tí wọ́n sì ń lọ láti ibi mímọ́ kí wọn sì gba ìyìn ní ìlú tàbí tí wọ́n ti ṣe èyí. Eléyìí pẹ̀lú kò ní ìtumọ̀. Nígbà tí a kò bá tètè ṣe ìdájọ́ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kíákíá, ọkàn àwọn ènìyàn a máa kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀ láti ṣe ibi. Bí ènìyàn búburú tó dẹ́ṣẹ̀ nígbà ọgọ́rùn-ún tilẹ̀ wà láààyè fún ìgbà pípẹ́, mo mọ̀ wí pé yóò dára fún ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó bẹ̀rù níwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dára fún ènìyàn búburú, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fa ọjọ́ rẹ̀ gún tí ó dà bí òjìji, nítorí tí kò bẹ̀rù níwájú Ọlọ́run. Ohun mìíràn tún wà tí kò ní ìtumọ̀, tí ó ń ṣẹlẹ̀ láyé olódodo tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí òṣìkà àti ènìyàn búburú tí ó ń gba ohun tí ó tọ́ sí olódodo. Mo sọ wí pé eléyìí gan an kò ní ìtumọ̀. Nítorí náà mo kan sáárá sí ìgbádùn ayé, nítorí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ní abẹ́ oòrùn ju pé kí ó jẹ, kí ó mu, kí inú rẹ̀ sì dùn lọ. Nígbà náà ni ìdùnnú yóò bá a rìn nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀, ní gbogbo ọjọ́ ayé ti Ọlọ́run tí fi fún un lábẹ́ oòrùn. Nígbà tí mo lo ọkàn mi láti mọ ọgbọ́n àti láti wo wàhálà ènìyàn ní ayé. Nígbà náà ni mo rí gbogbo ohun tí Ọlọ́run tí ṣe, kò sí ẹnìkan tí ó le è mòye ohun tí ó ń lọ lábẹ́ oòrùn. Láìbìkítà gbogbo ìyànjú rẹ̀ láti wá rí jáde, ènìyàn kò le è mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kódà bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn rò wí pé òun mọ̀ ọ́n, kò le è ní òye rẹ̀ ní pàtó.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa