Oni 7:20-22
Oni 7:20-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoriti kò si olõtọ enia lori ilẹ, ti nṣe rere ti kò si dẹṣẹ. Pẹlupẹlu máṣe fiyesi gbogbo ọ̀rọ ti a nsọ; ki iwọ ki o má ba gbọ́ ki iranṣẹ rẹ ki o bu ọ. Nitoripe nigba pupọ pẹlu li aiya rẹ mọ̀ pe iwọ tikalarẹ pẹlu ti bu awọn ẹlomiran.
Pín
Kà Oni 7Oni 7:20-22 Yoruba Bible (YCE)
Kò sí olódodo kan láyé tí ń ṣe rere, tí kò lẹ́ṣẹ̀. Má máa fetí sí gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan bá wí, kí o má baà gbọ́ pé iranṣẹ rẹ kan ń bú ọ. Ìwọ náà mọ̀ ní ọkàn rẹ pé, ní ọpọlọpọ ìgbà ni ìwọ náà ti bú eniyan rí.
Pín
Kà Oni 7Oni 7:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kò sí olódodo ènìyàn kan láyé tí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá. Má ṣe kíyèsi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ. Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnrarẹ̀ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmíràn.
Pín
Kà Oni 7