Oni 7:1-29

Oni 7:1-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

ORUKỌ rere dara jù ororo ikunra; ati ọjọ ikú jù ọjọ ibi enia lọ. O dara lati lọ si ile ọ̀fọ jù ati lọ si ile àse: nitoripe eyi li opin gbogbo enia; alãye yio si pa a mọ́ li aiya rẹ̀. Ibinujẹ san jù ẹrín: nitoripe nipa ifaro oju a si mu aiya san. Aiya ọlọgbọ́n mbẹ ni ile ọ̀fọ; ṣugbọn aiya aṣiwère ni ile iré. O san lati gbọ́ ibawi ọlọgbọ́n jù ki enia ki o fetisi orin aṣiwère. Nitoripe bi itapàpa ẹgún labẹ ìkoko, bẹ̃li ẹrín aṣiwère: asan li eyi pẹlu. Nitõtọ inilara mu ọlọgbọ́n enia sinwin; ọrẹ a si ba aiya jẹ. Opin nkan san jù ipilẹṣẹ rẹ̀ lọ: ati onisuru ọkàn jù ọlọkàn igberaga. Máṣe yara li ọkàn rẹ lati binu, nitoripe ibinu simi li aiya aṣiwère. Iwọ máṣe wipe, nitori kili ọjọ iṣaju ṣe san jù wọnyi lọ? nitoripe iwọ kò fi ọgbọ́n bere niti eyi. Ọgbọ́n dara gẹgẹ bi iní, ati nipasẹ rẹ̀ ère wà fun awọn ti nri õrùn. Nitoripe ãbò li ọgbọ́n, ani bi owo ti jẹ́ abò: ṣugbọn ère ìmọ ni pe, ọgbọ́n fi ìye fun awọn ti o ni i. Wò iṣẹ Ọlọrun: nitoripe, tali o le mu eyini tọ́ ti on ṣe ni wiwọ? Li ọjọ alafia, mã yọ̀, ṣugbọn li ọjọ ipọnju, ronu pe, bi Ọlọrun ti da ekini bẹ̃li o da ekeji, niti idi eyi pe ki enia ki o máṣe ri nkan ti mbọ̀ lẹhin rẹ̀. Ohun gbogbo ni mo ri li ọjọ asan mi: olõtọ enia wà ti o ṣegbé ninu ododo rẹ̀, ati enia buburu wà ti ọjọ rẹ̀ pẹ ninu ìwa buburu rẹ̀. Iwọ máṣe ododo aṣeleke; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fi ara rẹ ṣe ọlọgbọ́n aṣeleke: nitori kini iwọ o ṣe run ara rẹ? Iwọ máṣe buburu aṣeleke, bẹ̃ni ki iwọ ki o má ṣiwère; nitori kini iwọ o ṣe kú ki ọjọ rẹ ki o to pe? O dara ki iwọ ki o dì eyi mu; pẹlupẹlu iwọ máṣe yọ ọwọ rẹ kuro ninu eyi: nitori ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun ni yio yọ kuro ninu rẹ̀ gbogbo. Ọgbọ́n mu ọlọgbọ́n lara le jù enia alagbara mẹwa lọ ti o wà ni ilu. Nitoriti kò si olõtọ enia lori ilẹ, ti nṣe rere ti kò si dẹṣẹ. Pẹlupẹlu máṣe fiyesi gbogbo ọ̀rọ ti a nsọ; ki iwọ ki o má ba gbọ́ ki iranṣẹ rẹ ki o bu ọ. Nitoripe nigba pupọ pẹlu li aiya rẹ mọ̀ pe iwọ tikalarẹ pẹlu ti bu awọn ẹlomiran. Idi gbogbo wọnyi ni mo fi ọgbọ́n wá; mo ni, emi o gbọ́n: ṣugbọn ọ̀na rẹ̀ jin si mi. Eyi ti o jinna, ti o si jinlẹ gidigidi, tali o le wá a ri? Mo fi aiya mi si i lati mọ̀, on ati wadi, on ati ṣe afẹri ọgbọ́n ati oye, on ati mọ̀ ìwa buburu wère, ani ti wère ati ti isinwin: Mo si ri ohun ti o korò jù ikú lọ, ani obinrin ti aiya rẹ̀ iṣe idẹkun ati àwọn, ati ọwọ rẹ̀ bi ọbára: ẹnikẹni ti inu Ọlọrun dùn si yio bọ lọwọ rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹṣẹ li a o ti ọwọ rẹ̀ mu. Kiyesi i, eyi ni mo ri, bẹ̃li oniwasu wi, ni wiwadi rẹ̀ li ọkọkan lati ri oye. Ti ọkàn mi nwakiri sibẹ, ṣugbọn emi kò ri: ọkunrin kanṣoṣo ninu ẹgbẹrun ni mo ri; ṣugbọn obinrin kan ninu gbogbo awọn wọnni, emi kò ri. Kiyesi i, eyi nikanṣoṣo ni mo ri, pe, Ọlọrun ti da enia ni iduroṣinṣin; ṣugbọn nwọn ti ṣe afẹri ihumọkihumọ.

Oni 7:1-29 Yoruba Bible (YCE)

Orúkọ rere dára ju òróró olówó iyebíye lọ, ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ ìbí lọ. Ó dára láti lọ sí ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ju ati lọ sí ibi àsè lọ, nítorí pé àwọn alààyè gbọdọ̀ máa rán ara wọn létí pé ikú ni òpin gbogbo eniyan. Gbogbo alààyè ni wọ́n gbọdọ̀ máa fi èyí sọ́kàn. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ; lóòótọ́ ó lè mú kí ojú fàro, ṣugbọn a máa mú ayọ̀ bá ọkàn. Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn ọkàn òmùgọ̀ wà ní ibi ìgbádùn. Ó dára kí eniyan fetí sí ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju láti máa gbọ́ orin ìyìn àwọn òmùgọ̀ lọ. Bí ẹ̀gún ṣe máa ń ta ninu iná, lábẹ́ ìkòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín òmùgọ̀ rí. Asán ni èyí pẹlu. Dájúdájú, ìwà ìrẹ́jẹ a máa mú kí ọlọ́gbọ́n eniyan dàbí òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a sì máa ra eniyan níyè. Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, sùúrù sì dára ju ìwà ìgbéraga lọ. Má máa yára bínú, nítorí àyà òmùgọ̀ ni ibinu dì sí. Má máa bèèrè pé, “Kí ló dé tí ìgbà àtijọ́ fi dára ju ti ìsinsìnyìí lọ?” Irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́. Ọgbọ́n dára bí ogún, a máa ṣe gbogbo eniyan ní anfaani. Nítorí pé bí ọgbọ́n ṣe jẹ́ ààbò, bẹ́ẹ̀ ni owó náà jẹ́ ààbò; anfaani ìmọ̀ ni pé, ọgbọ́n a máa dáàbò bo ọlọ́gbọ́n. Ẹ kíyèsí ọgbọ́n Ọlọrun, nítorí pé, ta ló lè tọ́ ohun tí ó bá dá ní wíwọ́? Máa yọ̀ nígbà tí ó bá dára fún ọ, ṣugbọn nígbà tí nǹkan kò bá dára, máa ranti pé Ọlọrun ló ṣe mejeeji. Nítorí náà, eniyan kò lè mọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. Ninu gbogbo ìgbé-ayé asán mi, mo ti rí àwọn nǹkan wọnyi: Mo ti rí olódodo tí ó ṣègbé ninu òdodo rẹ̀, mo sì ti rí eniyan burúkú tí ẹ̀mí rẹ̀ gùn, pẹlu bí ó ti ń ṣe ibi. Má jẹ́ kí òdodo rẹ pọ̀ jù, má sì gbọ́n ní àgbọ́njù; kí ni o fẹ́ pa ara rẹ fún? Má ṣe burúkú jù, má sì jẹ́ òmùgọ̀. Ki ni o fẹ́ pa ara rẹ lọ́jọ́ àìpé fún? Di ekinni mú ṣinṣin, má sì jẹ́ kí ekeji bọ́ lọ́wọ́ rẹ; nítorí ẹni tí ó bá bẹ̀rù Ọlọrun yóo ní ìlọsíwájú. Ọgbọ́n yóo mú ọlọ́gbọ́n lágbára ju ọba mẹ́wàá lọ láàrin ìlú. Kò sí olódodo kan láyé tí ń ṣe rere, tí kò lẹ́ṣẹ̀. Má máa fetí sí gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan bá wí, kí o má baà gbọ́ pé iranṣẹ rẹ kan ń bú ọ. Ìwọ náà mọ̀ ní ọkàn rẹ pé, ní ọpọlọpọ ìgbà ni ìwọ náà ti bú eniyan rí. Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo ti fi ọgbọ́n wádìí. Mo sọ ninu ara mi pé, “Mo fẹ́ gbọ́n,” ṣugbọn ọgbọ́n jìnnà sí mi. Ta ló lè ṣe àwárí ohun tó jìnnà gbáà, tí ó jinlẹ̀ gan-an? Mo tún pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́, láti ṣe ìwádìí, ati láti wá ọgbọ́n, kí n mọ gbogbo nǹkan, ati ibi tí ń bẹ ninu ìwà òmùgọ̀, ati àìlóye tí ó wà ninu ìwà wèrè. Mo rí i pé, nǹkankan wà tí ó burú ju ikú lọ: òun ni obinrin oníṣekúṣe. Ọkàn rẹ̀ dàbí tàkúté ati àwọ̀n, tí ọwọ́ rẹ̀ dàbí ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun kò ní bọ́ sọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kó sinu tàkúté rẹ̀. Ohun tí mo rí nìyí, lẹ́yìn tí mo farabalẹ̀ ṣe ìwádìí pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, òun ni mò ń rò nígbà gbogbo, sibẹ, ó ṣì ń rú mi lójú: Láàrin ẹgbẹrun ọkunrin a lè rí ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ eniyan rere, ṣugbọn ninu gbogbo àwọn obinrin, kò sí ẹnìkan. Ẹ̀kọ́ tí mo rí kọ́ ni pé rere ni Ọlọrun dá eniyan, ṣugbọn àwọn ni wọ́n wá oríṣìíríṣìí ọ̀nà àrékérekè fún ara wọn.

Oni 7:1-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju ibi àsè nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn kí alààyè ní èyí ní ọkàn. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ, ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le. Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá. Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò ni ẹ̀rín òmùgọ̀, Asán sì ni eléyìí pẹ̀lú. Ìrẹ́jẹ a máa sọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni. Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, sùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ. Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé. Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?” Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dára ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní. Ọgbọ́n jẹ́ ààbò gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní. Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe: “Ta ni ó le è to ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?” Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn, ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó Ọlọ́run tí ó dá èkínní náà ni ó dá èkejì nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀. Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí: Ènìyàn olóòtítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀ ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀. Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run? Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè Èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé Ó dára láti mú ọ̀kan kí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀ Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè. Ọgbọ́n máa ń mú kí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára ju alákòóso mẹ́wàá lọ ní ìlú. Kò sí olódodo ènìyàn kan láyé tí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá. Má ṣe kíyèsi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ. Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnrarẹ̀ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmíràn. Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé, “Mo pinnu láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n” ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ. Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́, ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀ ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀? Mo wá rò ó nínú ọkàn mi láti mọ̀, láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́n àti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ ìwà àgọ́ búburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀. Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọ obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì, tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkúté tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n, ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni dẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀. Oniwaasu wí pé, “Wò ó” eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí: “Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo. Nígbà tí mo sì ń wá a kiri ṣùgbọ́n tí n kò rí i mo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrín ẹgbẹ̀rún ṣùgbọ́n n kò rí obìnrin, kankan kí ó dúró láàrín gbogbo wọn. Eléyìí nìkan ni mo tí ì rí: Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára, ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ̀.”