Oni 5:1-20

Oni 5:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

PA ẹsẹ rẹ mọ́ nigbati iwọ ba nlọ si ile Ọlọrun, ki iwọ ki o si mura ati gbọ́ jù ati ṣe irubọ aṣiwère: nitoriti nwọn kò rò pe nwọn nṣe ibi. Máṣe fi ẹnu rẹ yara, ki o má si jẹ ki aiya rẹ ki o yara sọ ọ̀rọ niwaju Ọlọrun: nitoriti Ọlọrun mbẹ li ọrun, iwọ si mbẹ li aiye: nitorina jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o mọ̀ ni ìwọn. Nitoripe nipa ọ̀pọlọpọ iṣẹ ni alá ti iwá; bẹ̃ni nipa ọ̀pọlọpọ ọ̀rọ li ã mọ̀ ohùn aṣiwère. Nigbati iwọ ba jẹ ẹjẹ́ fun Ọlọrun, máṣe duro pẹ lati san a: nitori kò ni inu-didun si aṣiwère: san eyi ti iwọ jẹjẹ́. O san ki iwọ ki o má jẹ ẹjẹ́, jù ki iwọ ki o jẹ ẹjẹ́, ki o má san a. Máṣe jẹ ki ẹnu rẹ ki o mu ara rẹ ṣẹ̀: ki iwọ ki o má si ṣe wi niwaju iranṣẹ Ọlọrun pe, èṣi li o ṣe: nitori kili Ọlọrun yio ṣe binu si ohùn rẹ, a si ba iṣẹ ọwọ rẹ jẹ? Nitoripe bi ninu ọ̀pọlọpọ alá ni asan wà, bẹ̃ni ninu ọ̀pọlọpọ ọ̀rọ pẹlu: ṣugbọn iwọ bẹ̀ru Ọlọrun. Bi iwọ ba ri inilara awọn olupọnju, ati ifi agbara yi idajọ ati otitọ pada ni igberiko, máṣe jẹ ki ẹnu ki o yà ọ si ọ̀ran na: nitoripe ẹniti o ga jù nṣọ ẹniti o ga, ati ẹni-giga-julọ wà lori wọn. Pẹlupẹlu ère ilẹ ni fun gbogbo enia: a si nsìn ọba tikalarẹ pãpa lati inu oko wa. Ẹniti o ba fẹ fadaka, fadaka kì yio tẹ́ ẹ lọrun; bẹ̃li ẹniti o fẹ ọrọ̀ kì yio tẹ́ ẹ lọrun: asan li eyi pẹlu. Nigbati ẹrù ba npọ̀ si i, awọn ti o si njẹ ẹ a ma pọ̀ si i: ore ki tilẹ ni fun ẹniti o ni i bikoṣepe ki nwọn ki o ma fi oju wọn wò o? Didùn ni orun oniṣẹ, iba jẹ onjẹ diẹ tabi pupọ: ṣugbọn itẹlọrun ọlọrọ̀ kì ijẹ, ki o sùn. Ibi buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, eyini ni pe, ọrọ̀ ti a pamọ́ fun ifarapa awọn ti o ni i. Nitori ọrọ̀ wọnni a ṣegbe nipa iṣẹ buburu; bi o si bi ọmọkunrin kan, kò ni nkan lọwọ rẹ̀. Bi o ti ti inu iya rẹ̀ jade wá, ihoho ni yio si tun pada lọ bi o ti wá, kì yio si mu nkan ninu lãla rẹ̀, ti iba mu lọ lọwọ rẹ̀. Ibi buburu li eyi pẹlu, pe li ọ̀na gbogbo, bi o ti wá, bẹ̃ni yio si lọ: ère ki si ni fun ẹniti nṣe lãla fun afẹfẹ? Li ọjọ rẹ̀ gbogbo pẹlu, o njẹun li òkunkun, o si ni ibinujẹ pupọ ati àrun ati irora rẹ̀. Kiyesi eyi ti mo ri: o dara o si yẹ fun enia, ki o jẹ, ki o si mu, ki o si ma jẹ alafia ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn, ni iye ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, ti Ọlọrun fi fun u: nitori eyi ni ipin tirẹ̀. Bi Ọlọrun ba fi ọrọ̀ fun ẹnikẹni, ti o si fun u li agbara ati jẹ ninu rẹ̀: ati lati mu ipin rẹ̀, ati lati yọ̀ ninu lãla rẹ eyi; pẹlu ẹ̀bun Ọlọrun ni. Nitoriti kì yio ranti ọjọ aiye rẹ̀ pọju; nitoriti Ọlọrun da a lohùn ninu ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

Oni 5:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Ṣọ́ra, nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọrun, ó sàn kí o lọ máa kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ ju pé kí o lọ máa rúbọ bí àwọn aṣiwèrè tí ń ṣe, tí wọn kò sì mọ̀ pé nǹkan burúkú ni àwọn ń ṣe. Má fi ẹnu rẹ sọ ìsọkúsọ, má sì kánjú sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọrun, nítorí Ọlọrun ń bẹ lọ́run ìwọ sì wà láyé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níwọ̀n. Ọpọlọpọ àkóléyà ní ń mú kí eniyan máa lá àlákálàá, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni eniyan sì fi ń mọ òmùgọ̀. Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Ọlọrun, má fi falẹ̀, tètè san án, nítorí kò ní inú dídùn sí àwọn òmùgọ̀. Ó sàn kí o má jẹ́ ẹ̀jẹ́ rárá ju pé kí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí o má mú un ṣẹ lọ. Má jẹ́ kí ẹnu rẹ mú ọ dẹ́ṣẹ̀, kí o má baà lọ máa yí ohùn pada lọ́dọ̀ iranṣẹ Ọlọrun pé, èèṣì ló ṣe. Má jẹ́ kí Ọlọrun bínú sí ọ, kí ó má baà pa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ run. Nígbà tí àlá bá pọ̀ ọ̀rọ̀ náà yóo pọ̀. Ṣugbọn pataki ni pé, ǹjẹ́ o tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọrun? Bí o bá wà ní agbègbè tí wọ́n ti ń pọ́n talaka lójú, tí kò sì sí ìdájọ́ òdodo ati ẹ̀tọ́, má jẹ́ kí èyí yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí ẹni tí ó ga ju ọ̀gá àgbà lọ ń ṣọ́ ọ̀gá àgbà. Ẹni tó tún ga ju àwọn náà lọ tún ń ṣọ́ gbogbo wọn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, anfaani ni ilẹ̀ tí à ń dáko sí jẹ́ fún ọba. Kò sí iye tó lè tẹ́ ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó lọ́rùn; bákan náà ni ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọrọ̀, kò sí iye tí ó lè jẹ lérè tí yóo tẹ́ ẹ lọ́rùn. Asán ni èyí pẹlu. Bí ọrọ̀ bá ti ń pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn tí yóo máa lò ó yóo máa pọ̀ sí i. Kò sì sí èrè tí ọlọ́rọ̀ yìí ní ju pé ó fi ojú rí ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Oorun dídùn ni oorun alágbàṣe, kì báà yó, kì báà má yó; ṣugbọn ìrònú ọrọ̀ kì í jẹ́ kí ọlọ́rọ̀ sùn lóru. Nǹkankan ń ṣẹlẹ̀, tí ó burú, tí mo ṣàkíyèsí láyé yìí, àwọn eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ fún ìpalára ara wọn. Àdáwọ́lé wọn lè yí wọn lọ́wọ́, wọ́n sì lè fi bẹ́ẹ̀ pàdánù ọrọ̀ wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè rí nǹkankan fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn. Bí eniyan ti wáyé níhòòhò láìmú nǹkankan lọ́wọ́ wá bẹ́ẹ̀ ni yóo pada, láìmú nǹkankan lọ́wọ́ lọ, bí èrè làálàá tí a ṣe láyé. Nǹkan burúkú gan-an ni èyí pàápàá jẹ́; pé bí a ṣe wá bẹ́ẹ̀ ni a óo ṣe lọ. Tabi èrè wo ni ó wà ninu pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo làálàá wa láyé. Ninu òkùnkùn, ati ìbànújẹ́ ni a ti ń lo ìgbésí ayé wa, pẹlu ọpọlọpọ ìyọnu, àìsàn ati ibinu. Wò ó! Ohun tí mo rí pé ó dára jù, tí ó sì yẹ, ni pé kí eniyan jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn gbogbo làálàá tí ó ń ṣe láyé, ní ìwọ̀nba ọjọ́ tí Ọlọrun fún un, nítorí èyí ni ìpín rẹ̀. Gbogbo ẹni tí Ọlọrun bá fún ní ọrọ̀ ati ohun ìní, ati agbára láti gbádùn wọn, ati láti gba ìpín rẹ̀ kí ó sì láyọ̀ ninu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ̀bùn Ọlọrun ni. Kò ní ranti iye ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí pé, Ọlọrun ti fi ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀.

Oni 5:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣọ́ ìrìn rẹ nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run. Kí ìwọ kí ó sì múra láti gbọ́ ju àti ṣe ìrúbọ aṣiwèrè, tí kò mọ̀ wí pé òun ń ṣe búburú. Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹ, má sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́run Ọlọ́run ń bẹ ní ọ̀run ìwọ sì wà ní ayé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìlépa púpọ̀ wà bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù. Nígbà tí o bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pẹ́ ní mímúṣẹ, kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ. Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ. Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé ìsìn pé “Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi.” Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ, kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́? Asán ni ọ̀pọ̀ àlá àti ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà dúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Bí o bá rí tálákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú púpọ̀, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ lójú ni, síbẹ̀ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì. Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko. Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó kì í ní owó ànító, ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ sí ọrọ̀ kì í ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú èrè tí ó ń wọlé fún un. Bí ẹrù bá ti ń pọ̀ sí i náà ni àwọn tí ó ń jẹ ẹ́ yóò máa pọ̀ sí i Èrè e kí ni wọ́n sì jẹ́ sí ẹni tí ó ni nǹkan bí kò ṣe pé, kí ó máa mú inú ara rẹ dùn nípa rí rí wọn? Oorun alágbàṣe a máa dùn, yálà ó jẹun kékeré ni tàbí ó jẹun púpọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn rárá. Mo ti rí ohun tí ó burú gidigidi lábẹ́ oòrùn ọrọ̀ tí a kó pamọ́ fún ìparun ẹni tó ni nǹkan. Tàbí ọrọ̀ tí ó sọnù nípa àìrí ojúrere, nítorí wí pé bí ó bá ní ọmọkùnrin kò sí ohun tí yóò fi sílẹ̀ fún un. Ìhòhò ni ènìyàn wá láti inú ìyá rẹ̀, bí ó sì ṣe wá, bẹ́ẹ̀ ni yóò kúrò kò sí ohunkóhun nínú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó le mú ní ọwọ́ rẹ̀. Ohun búburú gbá à ni eléyìí pàápàá: Bí ènìyàn ṣe wá, ni yóò lọ kí wá ni èrè tí ó jẹ nígbà tí ó ṣe wàhálà fún afẹ́fẹ́? Ó ń jẹ nínú òkùnkùn ní gbogbo ọjọ́ ọ rẹ̀, pẹ̀lú iyè ríra tí ó ga, ìnira àti ìbínú. Nígbà náà ni mo wá rí i dájú pé, ó dára, ó sì tọ̀nà fún ènìyàn láti jẹ, kí ó mu, kí ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ̀ lábẹ́ oòrùn, ní àkókò ọjọ́ ayé díẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún un, nítorí ìpín rẹ̀ ni èyí. Síwájú sí, nígbà tí Ọlọ́run fún ẹnikẹ́ni ní ọrọ̀ àti ohun ìní, tí ó sì fún un lágbára láti gbádùn wọn, láti gba ìpín rẹ̀ kí inú rẹ̀ sì dùn sí iṣẹ́ rẹ—ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí. Ó máa ń ronú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nípa ọjọ́ ayé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé Ọlọ́run ń pa á mọ́ pẹ̀lú inú dídùn ní ọkàn rẹ̀.