Oni 2:7-8
Oni 2:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo ni iranṣẹ-kọnrin ati iranṣẹ-birin, mo si ni ibile; mo si ni ini agbo malu ati agutan nlanla jù gbogbo awọn ti o wà ni Jerusalemu ṣaju mi. Mo si kó fadaka ati wura jọ ati iṣura ti ọba ati ti igberiko, mo ni awọn olorin ọkunrin ati olorin obinrin, ati didùn inu ọmọ enia, aya ati obinrin pupọ.
Oni 2:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Mo ra ọpọlọpọ ẹrukunrin ati ẹrubinrin, mo sì ní àwọn ọmọ ẹrú tí wọn bí ninu ilé mi, mo ní ọpọlọpọ agbo mààlúù ati agbo ẹran, ju àwọn tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ. Mo kó fadaka ati wúrà jọ fún ara mi; mo gba ìṣúra àwọn ọba ati ti àwọn agbègbè ìjọba mi. Mo ní àwọn akọrin lọkunrin ati lobinrin, mo sì ní ọpọlọpọ obinrin tíí mú inú ọkunrin dùn.
Oni 2:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀.