Oni 2:25-26
Oni 2:25-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe tali o le jẹun, tabi tani pẹlu ti o le mọ̀ adùn jù mi lọ? Nitoripe Ọlọrun fun enia ti o tọ li oju rẹ̀ li ọgbọ́n, ati ìmọ ati ayọ̀: ṣugbọn ẹlẹṣẹ li o fi ìṣẹ́ fun, lati ma kó jọ ati lati ma tò jọ ki on ki o le ma fi fun ẹni rere niwaju Ọlọrun. Eyi pẹlu asan ni ati imulẹmofo.
Oni 2:25-26 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí láìsí àṣẹ rẹ̀, ta ló lè jẹun, tabi kí ó gbádùn ohunkohun. Ọlọrun a máa fún ẹni tí ó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati inú dídùn; ṣugbọn iṣẹ́ àtikójọ ati àtitòjọ níí fún ẹlẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè fún àwọn tí ó bá wu Ọlọrun. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.
Oni 2:25-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí wí pé láìsí òun, ta ni ó le jẹ tàbí kí ó mọ adùn? Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.