Oni 2:22-25
Oni 2:22-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe kili enia ni ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o fi nṣe lãla labẹ õrùn? Nitoripe ọjọ rẹ̀ gbogbo, ikãnu ni, ati iṣẹ rẹ̀, ibinujẹ, nitõtọ aiya rẹ̀ kò simi li oru. Eyi pẹlu asan ni. Kò si ohun ti o dara fun enia jù ki o jẹ, ki o si mu ati ki o mu ọkàn rẹ̀ jadùn ohun rere ninu lãla rẹ̀. Eyi ni mo ri pẹlu pe, lati ọwọ Ọlọrun wá ni. Nitoripe tali o le jẹun, tabi tani pẹlu ti o le mọ̀ adùn jù mi lọ?
Oni 2:22-25 Yoruba Bible (YCE)
Kí ni eniyan rí gbà ninu gbogbo làálàá rẹ̀, kí sì ni èrè eniyan lórí akitiyan, ati iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé. Nítorí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ kún fún ìrora, iṣẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ ìbànújẹ́ fún un. Ọkàn rẹ̀ kì í balẹ̀ lóru, asán ni èyí pẹlu. Kò sí ohun tí ó dára fún eniyan ju kí ó jẹun kí ó sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lọ. Sibẹ mo rí i pé ọwọ́ Ọlọrun ni èyí tún ti ń wá. Nítorí láìsí àṣẹ rẹ̀, ta ló lè jẹun, tabi kí ó gbádùn ohunkohun.
Oni 2:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn? Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìsinmi ní alẹ́. Asán ni eléyìí pẹ̀lú. Ènìyàn kò le è ṣe ohunkóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run. Nítorí wí pé láìsí òun, ta ni ó le jẹ tàbí kí ó mọ adùn?