Oni 2:18-26

Oni 2:18-26 Yoruba Bible (YCE)

Mo kórìíra làálàá tí mo ti ṣe láyé, nígbà tí mo rí i pé n óo fi í sílẹ̀ fún ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Ta ni ó sì mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ni yóo jẹ́, tabi òmùgọ̀ eniyan? Sibẹsibẹ òun ni yóo jọ̀gá lórí gbogbo ohun tí mo fi ọgbọ́n mi kó jọ láyé yìí. Asán ni èyí pẹlu. Nítorí náà mo pada kábàámọ̀ lórí gbogbo ohun tí mo fi làálàá kójọ. Nítorí pé nígbà mìíràn ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹlu ọgbọ́n, ìmọ̀ ati òye yóo fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí kò ṣe làálàá fún wọn. Asán ni èyí pẹlu, nǹkan burúkú sì ni. Kí ni eniyan rí gbà ninu gbogbo làálàá rẹ̀, kí sì ni èrè eniyan lórí akitiyan, ati iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé. Nítorí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ kún fún ìrora, iṣẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ ìbànújẹ́ fún un. Ọkàn rẹ̀ kì í balẹ̀ lóru, asán ni èyí pẹlu. Kò sí ohun tí ó dára fún eniyan ju kí ó jẹun kí ó sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lọ. Sibẹ mo rí i pé ọwọ́ Ọlọrun ni èyí tún ti ń wá. Nítorí láìsí àṣẹ rẹ̀, ta ló lè jẹun, tabi kí ó gbádùn ohunkohun. Ọlọrun a máa fún ẹni tí ó bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati inú dídùn; ṣugbọn iṣẹ́ àtikójọ ati àtitòjọ níí fún ẹlẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè fún àwọn tí ó bá wu Ọlọrun. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.

Oni 2:18-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mo kórìíra gbogbo ohun tí mo ti ṣiṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni. Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí aṣiwèrè? Síbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú. Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìsimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn. Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnrarẹ̀. Asán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá. Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn? Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìsinmi ní alẹ́. Asán ni eléyìí pẹ̀lú. Ènìyàn kò le è ṣe ohunkóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run. Nítorí wí pé láìsí òun, ta ni ó le jẹ tàbí kí ó mọ adùn? Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.