Oni 2:18-21
Oni 2:18-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitõtọ mo korira gbogbo lãla mi ti mo ṣe labẹ õrùn: nitoriti emi o fi i silẹ fun enia ti mbọ̀ lẹhin mi. Tali o si mọ̀ bi ọlọgbọ́n ni yio ṣe tabi aṣiwère? sibẹ on ni yio ṣe olori iṣẹ mi gbogbo ninu eyi ti mo ṣe lãla, ati ninu eyi ti mo fi ara mi hàn li ọlọgbọ́n labẹ õrùn. Asan li eyi pẹlu. Nitorina mo kirilọ lati mu aiya mi ṣí kuro ninu gbogbo lãla mi ti mo ṣe labẹ õrùn. Nitoriti enia kan mbẹ, iṣẹ ẹniti o wà li ọgbọ́n ati ni ìmọ, ati ni iṣedẽde; sibẹ ẹniti kò ṣe lãla ninu rẹ̀ ni yio fi i silẹ fun ni ipin rẹ̀. Eyi pẹlu asan ni ati ibi nlanla.
Oni 2:18-21 Yoruba Bible (YCE)
Mo kórìíra làálàá tí mo ti ṣe láyé, nígbà tí mo rí i pé n óo fi í sílẹ̀ fún ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi. Ta ni ó sì mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ni yóo jẹ́, tabi òmùgọ̀ eniyan? Sibẹsibẹ òun ni yóo jọ̀gá lórí gbogbo ohun tí mo fi ọgbọ́n mi kó jọ láyé yìí. Asán ni èyí pẹlu. Nítorí náà mo pada kábàámọ̀ lórí gbogbo ohun tí mo fi làálàá kójọ. Nítorí pé nígbà mìíràn ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹlu ọgbọ́n, ìmọ̀ ati òye yóo fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí kò ṣe làálàá fún wọn. Asán ni èyí pẹlu, nǹkan burúkú sì ni.
Oni 2:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo kórìíra gbogbo ohun tí mo ti ṣiṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni. Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí aṣiwèrè? Síbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú. Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìsimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn. Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnrarẹ̀. Asán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá.