Oni 11:3-6
Oni 11:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi awọsanma ba kún fun òjo, nwọn a si tu dà si aiye: bi igi ba si wó sìha gusu tabi siha ariwa, nibiti igi na gbe ṣubu si, nibẹ ni yio si ma gbe. Ẹniti o nkiyesi afẹfẹ kì yio funrugbin; ati ẹniti o si nwòju awọsanma kì yio ṣe ikore. Bi iwọ kò ti mọ ipa-ọ̀na afẹfẹ, tabi bi egungun ti idàgba ninu aboyun: ani bẹ̃ni iwọ kò le mọ̀ iṣẹ Ọlọrun ti nṣe ohun gbogbo. Ni kutukutu fún irugbin rẹ, ati li aṣãlẹ máṣe da ọwọ rẹ duro: nitori ti iwọ kò mọ̀ eyi ti yio ṣe rere, yala eyi tabi eyini, tabi bi awọn mejeji yio dara bakanna.
Oni 11:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí òjò bá ṣú dẹ̀dẹ̀, orí ilẹ̀ ni yóo rọ̀ sí, níbi tí igi bá wó sí, níbẹ̀ náà ni yóo wà. Ẹni tí ń wo ojú afẹ́fẹ́ kò ní fún irúgbìn kankan, ẹni tí ó bá sì ń wo ṣúṣú òjò kò ní kórè. Gẹ́gẹ́ bí o kò ti mọ bí ẹ̀mí ṣe ń wọ inú ọmọ ninu aboyún, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ bí Ọlọrun ṣe dá ohun gbogbo. Fún irúgbìn ní àárọ̀, má sì ṣe dáwọ́ dúró ní ìrọ̀lẹ́, nítorí o kò mọ èyí tí yóo dàgbà, bóyá ti òwúrọ̀ ni tabi ti ìrọ̀lẹ́, tabi àwọn mejeeji.
Oni 11:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi, ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́, nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere bóyá èyí tàbí ìyẹn tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà.