Oni 11:1-10

Oni 11:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Gbin nǹkan ọ̀gbìn káàkiri lọpọlọpọ, o óo sì kórè ọpọlọpọ èso nígbà tó bá yá. Gbin àwọn kan síhìn-ín, gbin àwọn kan sọ́hùn-ún, gbìn ín káàkiri oko nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. Nígbà tí òjò bá ṣú dẹ̀dẹ̀, orí ilẹ̀ ni yóo rọ̀ sí, níbi tí igi bá wó sí, níbẹ̀ náà ni yóo wà. Ẹni tí ń wo ojú afẹ́fẹ́ kò ní fún irúgbìn kankan, ẹni tí ó bá sì ń wo ṣúṣú òjò kò ní kórè. Gẹ́gẹ́ bí o kò ti mọ bí ẹ̀mí ṣe ń wọ inú ọmọ ninu aboyún, bẹ́ẹ̀ ni o kò mọ̀ bí Ọlọrun ṣe dá ohun gbogbo. Fún irúgbìn ní àárọ̀, má sì ṣe dáwọ́ dúró ní ìrọ̀lẹ́, nítorí o kò mọ èyí tí yóo dàgbà, bóyá ti òwúrọ̀ ni tabi ti ìrọ̀lẹ́, tabi àwọn mejeeji. Ìmọ́lẹ̀ dára, oòrùn sì dùn-ún wò. Bí eniyan ti wù kí ó pẹ́ láyé tó, kí ó máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, ṣugbọn kí ó ranti pé ọjọ́ tí òun yóo lò ninu ibojì yóo pọ̀ ju èyí tí òun yóo lò láyé lọ. Asán ni ìgbẹ̀yìn gbogbo ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Ìwọ ọdọmọkunrin, máa yọ̀ ní ìgbà èwe rẹ, kí inú rẹ máa dùn; máa ṣe bí ọkàn rẹ ti ń fẹ́, ati bí ó ti tọ́ lójú rẹ. Ṣugbọn ranti pé, Ọlọrun yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ohun tí o bá ṣe. Gbé ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn rẹ, má sì gba ìrora láàyè lára rẹ, nítorí asán ni ìgbà èwe ati ìgbà ọmọde.

Oni 11:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Fún àkàrà rẹ sórí omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò rí i padà Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú, nítorí ìwọ kò mọ ohun ìparun tí ó le è wá sórí ilẹ̀. Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi, ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́, nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere bóyá èyí tàbí ìyẹn tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà. Ìmọ́lẹ̀ dùn; Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún tí ó le è lò láyé ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn nítorí wọn ó pọ̀ Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni. Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwe kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ. Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹ àti ohunkóhun tí ojú rẹ rí ṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́. Nítorí náà, mú ìjayà kúrò ní ọkàn rẹ kí o sì lé ìbànújẹ́ ara rẹ kúrò nítorí èwe àti kékeré kò ní ìtumọ̀.