Oni 1:7-9
Oni 1:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Odò gbogbo ni nṣan sinu okun; ṣugbọn okun kò kún, nibiti awọn odò ti nṣàn wá, nibẹ ni nwọn si tun pada lọ. Ọ̀rọ gbogbo kò to; enia kò le sọ ọ: iran kì isu oju, bẹ̃li eti kì ikún fun gbigbọ́. Ohun ti o wà, on ni yio si wà; ati eyiti a ti ṣe li eyi ti a o ṣe; kò si ohun titun labẹ õrùn.
Oni 1:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Inú òkun ni gbogbo odò tí ń ṣàn ń lọ, ṣugbọn òkun kò kún. Ibi tí àwọn odò ti ń ṣàn wá, ibẹ̀ ni wọ́n tún ṣàn pada lọ. Gbogbo nǹkan ní ń kó àárẹ̀ bá eniyan, ju bí ẹnu ti lè sọ lọ. Ìran kì í sú ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ kì í kún etí. Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóo máa wà. Ohun tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀ náà ni a óo tún máa ṣe, kò sí ohun titun kan ní ilé ayé.
Oni 1:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo odò ń sàn sí inú Òkun, síbẹ̀síbẹ̀ Òkun kò kún. Níbi tí àwọn odò ti wá, níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí. Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá, ju èyí tí ẹnu le è sọ. Ojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́. Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìn òun ni a ó tún máa ṣe padà kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn.