Oni 1:12-18
Oni 1:12-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi oniwasu jọba lori Israeli ni Jerusalemu. Mo si fi aiya mi si ati ṣe afẹri on ati wadi ọgbọ́n niti ohun gbogbo ti a nṣe labẹ ọrun, lãla kikan yi li Ọlorun fi fun awọn ọmọ enia lati ṣe lãla ninu rẹ̀. Mo ti ri iṣẹ gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn; si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo. Eyi ti o wọ́, a kò le mu u tọ́: ati iye àbuku, a kò le kà a. Mo si ba aiya ara mi sọ̀rọ wipe, kiyesi i, mo li ọgbọ́n nla, mo si fi kún u jù gbogbo wọn lọ ti o ti ṣaju mi ni Jerusalemu; aiya mi si ri ohun pupọ nla niti ọgbọ́n ati ti ìmọ. Nigbati mo fi aiya mi si ati mọ̀ ọgbọ́n, ati lati mọ̀ isinwin ati iwère: nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi pẹlu jẹ imulẹmofo. Nitoripe ninu ọgbọ́n pupọ ni ibinujẹ pupọ wà, ẹniti o si nsọ ìmọ di pupọ, o nsọ ikãnu di pupọ.
Oni 1:12-18 Yoruba Bible (YCE)
Èmi ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ti jẹ ọba lórí Israẹli, ní Jerusalẹmu. Mo fi tọkàntọkàn pinnu láti fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ohun tí eniyan ń ṣe láyé. Làálàá lásán ni iṣẹ́ tí Ọlọrun fún ọmọ eniyan ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Mo ti wo gbogbo nǹkan tí eniyan ń ṣe láyé, wò ó, asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀. Ohun tí ó bá ti wọ́, ẹnìkan kò lè tọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò lè ka ohun tí kò bá sí. Mo wí lọ́kàn ara mi pé, “Mo ti kọ́ ọpọlọpọ ọgbọ́n, ju gbogbo àwọn tí wọ́n ti jọba ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ. Mo ní ọpọlọpọ ìrírí tí ó kún fún ọgbọ́n ati ìmọ̀.” Mo pinnu lọ́kàn mi láti mọ ohun tí ọgbọ́n jẹ́, ati láti mọ ohun tí ìwà wèrè ati ìwà òmùgọ̀ jẹ́. Mo wá wòye pé èyí pàápàá jẹ́ ìmúlẹ̀mófo. Nítorí pé ọpọlọpọ ọgbọ́n a máa mú ọpọlọpọ ìbànújẹ́ wá, ẹni tí ń fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, ó ń fi kún ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ ni.
Oni 1:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi, Oniwaasu ti jẹ ọba lórí Israẹli ní Jerusalẹmu rí. Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run. Háà! Ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn: Èmi ti rí ohun gbogbo tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, gbogbo rẹ̀ kò ní ìtumọ̀ bí ẹní gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni. Ohun tí ó ti wọ́ kò le è ṣe é tọ́ mọ́, ohun tí kò sí kò le è ṣe é kà. Mo rò nínú ara mi, “Wò ó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóso Jerusalẹmu síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀.” Nígbà náà ni mo fi ara jì láti ní ìmọ̀ nípa ọgbọ́n, àti pàápàá àìgbọ́n àti òmùgọ̀, ṣùgbọ́n mo rí, wí pé èyí pẹ̀lú bí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni. Nítorí pé ọgbọ́n púpọ̀ ìbànújẹ́ púpọ̀ ní ń mú wá, bí ìmọ̀ bá sì ṣe pọ̀ tó náà ni ìbànújẹ́ ń pọ̀ tó.