Oni 1:1-18

Oni 1:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀RỌ oniwasu, ọmọ Dafidi, ti o jọba ni Jerusalemu. Asan inu asan, oniwasu na wipe, asan inu asan; gbogbo rẹ̀ asan ni! Ere kili enia jẹ ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn? Iran kan lọ, iran miran si bọ̀: ṣugbọn aiye duro titi lai. Õrun pẹlu là, õrun si wọ̀, o si yara lọ si ipò rẹ̀ nibiti o ti là. Afẹfẹ nfẹ lọ siha gusu, a si yipada siha ariwa; o si nlọ sihin sọhun titi, afẹfẹ si tun pada gẹgẹ nipa ayika rẹ̀. Odò gbogbo ni nṣan sinu okun; ṣugbọn okun kò kún, nibiti awọn odò ti nṣàn wá, nibẹ ni nwọn si tun pada lọ. Ọ̀rọ gbogbo kò to; enia kò le sọ ọ: iran kì isu oju, bẹ̃li eti kì ikún fun gbigbọ́. Ohun ti o wà, on ni yio si wà; ati eyiti a ti ṣe li eyi ti a o ṣe; kò si ohun titun labẹ õrùn. Ohun kan wà nipa eyi ti a wipe, Wò o, titun li eyi! o ti wà na nigba atijọ, ti o ti wà ṣaju wa. Kò si iranti ohun iṣaju; bẹ̃ni iranti kì yio si fun ohun ikẹhin ti mbọ̀, lọdọ awọn ti mbọ̀ ni igba ikẹhin. Emi oniwasu jọba lori Israeli ni Jerusalemu. Mo si fi aiya mi si ati ṣe afẹri on ati wadi ọgbọ́n niti ohun gbogbo ti a nṣe labẹ ọrun, lãla kikan yi li Ọlorun fi fun awọn ọmọ enia lati ṣe lãla ninu rẹ̀. Mo ti ri iṣẹ gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn; si kiyesi i, asan ni gbogbo rẹ̀ ati imulẹmofo. Eyi ti o wọ́, a kò le mu u tọ́: ati iye àbuku, a kò le kà a. Mo si ba aiya ara mi sọ̀rọ wipe, kiyesi i, mo li ọgbọ́n nla, mo si fi kún u jù gbogbo wọn lọ ti o ti ṣaju mi ni Jerusalemu; aiya mi si ri ohun pupọ nla niti ọgbọ́n ati ti ìmọ. Nigbati mo fi aiya mi si ati mọ̀ ọgbọ́n, ati lati mọ̀ isinwin ati iwère: nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi pẹlu jẹ imulẹmofo. Nitoripe ninu ọgbọ́n pupọ ni ibinujẹ pupọ wà, ẹniti o si nsọ ìmọ di pupọ, o nsọ ikãnu di pupọ.

Oni 1:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Ọ̀rọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n, ọmọ Dafidi, Ọba Jerusalẹmu nìyí. Asán ninu asán, bí ọ̀jọ̀gbọ́n ti wí, asán ninu asán, gbogbo rẹ̀ asán ni. Èrè kí ni eniyan ń jẹ ninu gbogbo làálàá rẹ̀, tí ó ń ṣe nílé ayé? Ìran kan ń kọjá lọ, òmíràn ń dé, ṣugbọn ayé wà títí laelae. Oòrùn ń yọ, oòrùn ń wọ̀, ó sì ń yára pada sí ibi tí ó ti yọ wá. Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúsù, ó sì ń yípo lọ sí ìhà àríwá. Yíyípo ni afẹ́fẹ́ ń yípo, a sì tún pada sí ibi tí ó ti wá. Inú òkun ni gbogbo odò tí ń ṣàn ń lọ, ṣugbọn òkun kò kún. Ibi tí àwọn odò ti ń ṣàn wá, ibẹ̀ ni wọ́n tún ṣàn pada lọ. Gbogbo nǹkan ní ń kó àárẹ̀ bá eniyan, ju bí ẹnu ti lè sọ lọ. Ìran kì í sú ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ kì í kún etí. Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóo máa wà. Ohun tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀ náà ni a óo tún máa ṣe, kò sí ohun titun kan ní ilé ayé. Ǹjẹ́ ohun kankan wà tí a lè tọ́ka sí pé: “Wò ó! Ohun titun nìyí.” Ó ti wà rí ní ìgbà àtijọ́. Kò sí ẹni tí ó ranti àwọn nǹkan àtijọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni, kò sì ní sí ẹni tí yóo ranti àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. Èmi ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ti jẹ ọba lórí Israẹli, ní Jerusalẹmu. Mo fi tọkàntọkàn pinnu láti fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ohun tí eniyan ń ṣe láyé. Làálàá lásán ni iṣẹ́ tí Ọlọrun fún ọmọ eniyan ṣe lórí ilẹ̀ ayé. Mo ti wo gbogbo nǹkan tí eniyan ń ṣe láyé, wò ó, asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀. Ohun tí ó bá ti wọ́, ẹnìkan kò lè tọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò lè ka ohun tí kò bá sí. Mo wí lọ́kàn ara mi pé, “Mo ti kọ́ ọpọlọpọ ọgbọ́n, ju gbogbo àwọn tí wọ́n ti jọba ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ. Mo ní ọpọlọpọ ìrírí tí ó kún fún ọgbọ́n ati ìmọ̀.” Mo pinnu lọ́kàn mi láti mọ ohun tí ọgbọ́n jẹ́, ati láti mọ ohun tí ìwà wèrè ati ìwà òmùgọ̀ jẹ́. Mo wá wòye pé èyí pàápàá jẹ́ ìmúlẹ̀mófo. Nítorí pé ọpọlọpọ ọgbọ́n a máa mú ọpọlọpọ ìbànújẹ́ wá, ẹni tí ń fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, ó ń fi kún ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ ni.

Oni 1:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọ̀rọ̀ Oniwaasu, ọmọ Dafidi, ọba Jerusalẹmu: “Asán inú asán!” oníwàásù náà wí pé, “Asán inú asán! Gbogbo rẹ̀ asán ni.” Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn? Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ, síbẹ̀ ayé dúró títí láé. Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀, ó sì sáré padà sí ibi tí ó ti yọ. Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúúsù, Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá, a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀. Gbogbo odò ń sàn sí inú Òkun, síbẹ̀síbẹ̀ Òkun kò kún. Níbi tí àwọn odò ti wá, níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí. Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá, ju èyí tí ẹnu le è sọ. Ojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́. Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìn òun ni a ó tún máa ṣe padà kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn. Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è sọ wí pé, “Wò ó! Ohun tuntun ni èyí”? Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́, o ti wà ṣáájú tiwa. Kò sí ìrántí ohun ìṣáájú bẹ́ẹ̀ ni ìrántí kì yóò sí fún ohun ìkẹyìn tí ń bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn tí ń bọ̀ ní ìgbà ìkẹyìn. Èmi, Oniwaasu ti jẹ ọba lórí Israẹli ní Jerusalẹmu rí. Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run. Háà! Ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn: Èmi ti rí ohun gbogbo tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, gbogbo rẹ̀ kò ní ìtumọ̀ bí ẹní gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni. Ohun tí ó ti wọ́ kò le è ṣe é tọ́ mọ́, ohun tí kò sí kò le è ṣe é kà. Mo rò nínú ara mi, “Wò ó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóso Jerusalẹmu síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀.” Nígbà náà ni mo fi ara jì láti ní ìmọ̀ nípa ọgbọ́n, àti pàápàá àìgbọ́n àti òmùgọ̀, ṣùgbọ́n mo rí, wí pé èyí pẹ̀lú bí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni. Nítorí pé ọgbọ́n púpọ̀ ìbànújẹ́ púpọ̀ ní ń mú wá, bí ìmọ̀ bá sì ṣe pọ̀ tó náà ni ìbànújẹ́ ń pọ̀ tó.