Deu 8:17-18
Deu 8:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ a si wi li ọkàn rẹ pe, Agbara mi ati ipa ọwọ́ mi li o fun mi li ọrọ̀ yi. Ṣugbọn ki iwọ ki o ranti OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe, on li o fun ọ li agbara lati lí ọrọ̀, ki on ki o le fi idi majẹmu rẹ̀ ti o bura fun awọn baba rẹ kalẹ, bi o ti ri li oni yi.
Deu 8:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà sọ ninu ọkàn yín pé agbára yín, ati ipá yín ni ó mú ọrọ̀ yìí wá fun yín. Ẹ ranti OLUWA Ọlọrun yín nítorí òun ni ó fun yín ní agbára láti di ọlọ́rọ̀, kí ó lè fìdí majẹmu tí ó fi ìbúra bá àwọn baba yín dá múlẹ̀, bí ó ti rí lónìí.
Deu 8:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ lè rò nínú ara yín pé, “Agbára mi àti iṣẹ́ ọwọ́ mi ni ó mú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá fún mi.” Ṣùgbọ́n ẹ rántí OLúWA Ọlọ́run yín tí ó fún un yín ní agbára àti lè ní àwọn ọrọ̀ wọ̀nyí, tí ó sì fi mú májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá a yín bí ó ti rí lónìí.