Deu 8:12-14
Deu 8:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki iwọ ki o má ba jẹ yó tán, ki o kọ ile daradara, ki o si ma gbé inu rẹ̀; Ati ki ọwọ́-ẹran rẹ ati agbo-ẹran rẹ, ki o ma ba pọ̀si i tán, ki fadakà rẹ ati wurà rẹ pọ̀si i, ati ki ohun gbogbo ti iwọ ní pọ̀si i; Nigbana ni ki ọkàn rẹ wa gbé soke, iwọ a si gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú
Deu 8:12-14 Yoruba Bible (YCE)
kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun, tí ẹ yó tán, tí ẹ ti kọ́ àwọn ilé dáradára, tí ẹ sì ń gbé inú wọn, nígbà tí agbo mààlúù yín ati agbo aguntan yín bá pọ̀ sí i, tí wúrà ati fadaka yín náà sì pọ̀ sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní bá pọ̀ sí i, kí ìgbéraga má gba ọkàn yín, kí ẹ sì gbàgbé OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, níbi tí ẹ ti ń ṣe ẹrú.
Deu 8:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ó má ba à jẹ́ pé, nígbà tí ẹ bá jẹun yó tán, tí ẹ bá kọ́ ilé tí ó dára tán, tí ẹ sí ń gbé inú rẹ̀, nígbà tí àwọn agbo màlúù yín àti tí ewúrẹ́ ẹ yín bá pọ̀ sí i tán, tí fàdákà àti wúrà yín sì ń peléke sí i, tí ohun gbogbo tí ẹ ní sì ń pọ̀ sí i, nígbà náà ni ọkàn yín yóò gbéga, tí ẹ̀yin yóò sì gbàgbé OLúWA Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá, nínú oko ẹrú.