Deu 8:1-6
Deu 8:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
GBOGBO ofin ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati ṣe, ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹnyin si ma pọ̀ si i, ki ẹnyin si wọnu rẹ̀ lọ lati gbà ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin. Ki iwọ ki o si ranti ọ̀na gbogbo ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti mu ọ rìn li aginjù lati ogoji ọdún yi wá, lati rẹ̀ ọ silẹ, ati lati dan ọ wò, lati mọ̀ ohun ti o wà li àiya rẹ, bi iwọ o pa ofin rẹ̀ mọ́, bi bẹ̃kọ. O si rẹ̀ ọ silẹ, o si fi ebi pa ọ, o si fi manna bọ́ ọ, ti iwọ kò mọ̀, bẹ̃ni awọn baba rẹ kò mọ̀; ki o le mu ọ mọ̀ pe enia kò ti ipa onjẹ nikan wà lãye, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu OLUWA jade li enia wà lãye. Aṣọ rẹ kò gbó mọ́ ọ lara, bẹ̃li ẹsẹ̀ rẹ kò wú, lati ogoji ọdún yi wá. Ki iwọ ki o si mọ̀ li ọkàn rẹ pe, bi enia ti ibá ọmọ rẹ̀ wi, bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ wi. Ki iwọ ki o pa ofin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma bẹ̀ru rẹ̀.
Deu 8:1-6 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè máa bí sí i, kí ẹ sì lè lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA ti búra láti fún àwọn baba yín. Ẹ ranti gbogbo ọ̀nà tí OLUWA Ọlọrun yín ti mú yín tọ̀ ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún yìí wá, láti tẹ orí yín ba; ó dán yín wò láti rí ọkàn yín, bóyá ẹ óo pa òfin rẹ̀ mọ́ tabi ẹ kò ní pa á mọ́. Ó tẹ orí yín ba, ó jẹ́ kí ebi pa yín, ó fi mana tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí bọ́ yín, kí ẹ lè mọ̀ pé kìí ṣe oúnjẹ nìkan ní o lè mú kí eniyan wà láàyè, àfi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu OLUWA jáde. Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ yín kò wú, fún odidi ogoji ọdún yìí. Nítorí náà, ẹ mọ̀ ninu ara yín pé, gẹ́gẹ́ bí baba ti máa ń bá ọmọ rẹ̀ wí ni OLUWA ń ba yín wí. Nítorí náà, ẹ pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́, nípa rírìn ní ọ̀nà rẹ̀ ati bíbẹ̀rù rẹ̀.
Deu 8:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ kíyèsi i láti máa tẹ̀lé gbogbo àṣẹ tí mo fún un yín lónìí, kí ẹ bá à le yè, kí ẹ sì pọ̀ sí i wọ ilẹ̀ náà, kí ẹ sì le gba ilẹ̀ náà, tí OLúWA fì búra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín. Ẹ rántí bí OLúWA Ọlọ́run yín ti tọ́ ọ yín ṣọ́nà ní gbogbo ọ̀nà ní aginjù fún ogójì ọdún wọ̀nyí láti tẹ orí yín ba àti láti dán an yín wò kí ó ba à le mọ bí ọkàn yín ti rí, bóyá ẹ ó pa òfin rẹ̀ mọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó rẹ̀ yín sílẹ̀ nípa fífi ebi pa yín, Ó sì fi manna bọ́ ọ yín, èyí tí ẹ kò mọ̀, tí àwọn baba yín kò mọ̀, kí ó ba à lè kọ́ ọ yín pé, ènìyàn kò ti ipa oúnjẹ nìkan wà láààyè, bí kò ṣe ohun gbogbo tí ó jáde láti ẹnu OLúWA wá. Aṣọ yín kò gbó mọ́ ọn yín lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ní ẹsẹ̀ yín kò sì wú, ní ogójì ọdún náà. Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLúWA Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín. Nítorí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin OLúWA Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀.