Deu 7:7-11
Deu 7:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA kò fi ifẹ́ rẹ̀ si nyin lara, bẹ̃ni kò yàn nyin, nitoriti ẹnyin pọ̀ ni iye jù awọn enia kan lọ; nitoripe ẹnyin li o tilẹ kére jù ninu gbogbo enia: Ṣugbọn nitoriti OLUWA fẹ́ nyin, ati nitoriti on fẹ́ pa ara ti o ti bú fun awọn baba nyin mọ́, ni OLUWA ṣe fi ọwọ́ agbara mú nyin jade, o si rà nyin pada kuro li oko-ẹrú, kuro li ọwọ́ Farao ọba Egipti. Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ, on li Ọlọrun; Ọlọrun olõtọ, ti npa majẹmu mọ́ ati ãnu fun awọn ti o fẹ́ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ́ dé ẹgbẹrun iran; Ti o si nsan a pada fun awọn ti o korira rẹ̀ li oju wọn, lati run wọn: on ki yio jafara fun ẹniti o korira rẹ̀, on o san a fun u loju rẹ̀. Nitorina ki iwọ ki o pa ofin, ati ìlana, ati idajọ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe wọn.
Deu 7:7-11 Yoruba Bible (YCE)
“Kì í ṣe pé ẹ pọ̀ ju àwọn eniyan yòókù lọ ni OLUWA fi fẹ́ràn yín, tí ó sì fi yàn yín. Ninu gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yin ni ẹ kéré jùlọ. Ṣugbọn, nítorí pé OLUWA fẹ́ràn yín, ati nítorí ìbúra tí ó ti ṣe fún àwọn baba yín, ni ó ṣe fi agbára ko yín jáde, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú, lọ́wọ́ Farao, ọba Ijipti. Nítorí náà, ẹ máa ranti pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun, Ọlọrun olótìítọ́ tíí pa majẹmu mọ́, tíí sì ń fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn sí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, títí dé ẹgbẹrun ìran, a sì máa san ẹ̀san lojukooju fún àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀. Yóo pa wọ́n run, kò ní dáwọ́ dúró láti má gba ẹ̀san lára gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀, yóo san ẹ̀san fún wọn ní ojúkoojú. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra kí ẹ sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì tẹ̀lé ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí.
Deu 7:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ju àwọn ènìyàn yòókù lọ yàn yín, ẹ̀yin sá à lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn. Ṣùgbọ́n torí Ọlọ́run fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó ṣe fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Farao ọba Ejibiti. Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé OLúWA Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olóòtítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ni yóò san ẹ̀san fún ní gbangba nípa pípa wọ́n run; kì yóò sì jáfara láti san ẹ̀san fún àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ ní gbangba. Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa tẹ̀lé àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí mo fun un yín lónìí.