Deu 7:5-9
Deu 7:5-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bayi li ẹnyin o fi wọn ṣe; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn, ẹ o si bì ọwọ̀n wọn lulẹ, ẹ o si ke igbo oriṣa wọn lulẹ, ẹ o si fi iná jó gbogbo ere finfin wọn. Nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ: OLUWA Ọlọrun rẹ ti yàn ọ lati jẹ́ enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ. OLUWA kò fi ifẹ́ rẹ̀ si nyin lara, bẹ̃ni kò yàn nyin, nitoriti ẹnyin pọ̀ ni iye jù awọn enia kan lọ; nitoripe ẹnyin li o tilẹ kére jù ninu gbogbo enia: Ṣugbọn nitoriti OLUWA fẹ́ nyin, ati nitoriti on fẹ́ pa ara ti o ti bú fun awọn baba nyin mọ́, ni OLUWA ṣe fi ọwọ́ agbara mú nyin jade, o si rà nyin pada kuro li oko-ẹrú, kuro li ọwọ́ Farao ọba Egipti. Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ pe, OLUWA Ọlọrun rẹ, on li Ọlọrun; Ọlọrun olõtọ, ti npa majẹmu mọ́ ati ãnu fun awọn ti o fẹ́ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ́ dé ẹgbẹrun iran
Deu 7:5-9 Yoruba Bible (YCE)
Ohun tí ẹ óo ṣe sí wọn nìyí: ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ rún àwọn òpó wọn, ẹ gé àwọn oriṣa Aṣera wọn lulẹ̀, kí ẹ sì sun gbogbo àwọn ère wọn níná. Nítorí pé, ẹni mímọ́ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA Ọlọrun yín ti yàn yín, láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní gbogbo ayé, pé kí ẹ jẹ́ ohun ìní fún òun. “Kì í ṣe pé ẹ pọ̀ ju àwọn eniyan yòókù lọ ni OLUWA fi fẹ́ràn yín, tí ó sì fi yàn yín. Ninu gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yin ni ẹ kéré jùlọ. Ṣugbọn, nítorí pé OLUWA fẹ́ràn yín, ati nítorí ìbúra tí ó ti ṣe fún àwọn baba yín, ni ó ṣe fi agbára ko yín jáde, tí ó sì rà yín pada kúrò ní oko ẹrú, lọ́wọ́ Farao, ọba Ijipti. Nítorí náà, ẹ máa ranti pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun, Ọlọrun olótìítọ́ tíí pa majẹmu mọ́, tíí sì ń fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn sí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, títí dé ẹgbẹrun ìran
Deu 7:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni kí ẹ ṣe sí wọn: Ẹ wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ bi òpó òkúta ibi mímọ́ òrìṣà wọn lulẹ̀, òpó òrìṣà Aṣerah wọn ni kí ẹ gé lulẹ̀ kí ẹ sì sun ère òrìṣà wọn ní iná. Torí pé ènìyàn mímọ́ ni ẹ jẹ́ sí OLúWA Ọlọ́run yín, OLúWA Ọlọ́run yín ti yàn yín láàrín gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, láti jẹ́ ènìyàn rẹ̀: ohun ìní iyebíye rẹ̀. OLúWA kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ju àwọn ènìyàn yòókù lọ yàn yín, ẹ̀yin sá à lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn. Ṣùgbọ́n torí Ọlọ́run fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó ṣe fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Farao ọba Ejibiti. Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé OLúWA Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olóòtítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.