Deu 4:9-10
Deu 4:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kìki ki iwọ ki o ma kiyesara rẹ, ki o si ṣọ́ ọkàn rẹ gidigidi, ki iwọ ki o má ba gbagbé ohun ti oju rẹ ti ri, ati ki nwọn ki o má ba lọ kuro li àiya rẹ li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ṣugbọn ki iwọ ki o ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ; Li ọjọ́ ti iwọ duro niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu, nigbati OLUWA wi fun mi pe, Pe awọn enia yi jọ fun mi, emi o si mu wọn gbọ́ ọ̀rọ mi, ki nwọn ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru mi li ọjọ́ gbogbo ti nwọn o wà lori ilẹ, ati ki nwọn ki o le ma kọ́ awọn ọmọ wọn.
Deu 4:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ má baà gbàgbé àwọn ohun tí ẹ ti fi ojú ara yín rí, kí iyè yín má baà fò wọ́n ní gbogbo ọjọ́ ayé yín. Ẹ máa pa á nítàn fún àwọn ọmọ yín ati àwọn ọmọ ọmọ yín, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lẹ́bàá òkè Sinai, tí ó fi sọ fún mi pé, ‘Pe àwọn eniyan náà jọ sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bẹ̀rù mi ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn; kí wọ́n sì kọ́ àwọn ọmọ wọn pẹlu.’
Deu 4:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì ṣọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láààyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn. Ẹ rántí ọjọ́ tí ẹ dúró níwájú OLúWA Ọlọ́run yín ní Horebu, nígbà tí ó wí fún mi pé, “Kó àwọn ènìyàn wọ̀nyí jọ síwájú mi láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọ́n lè kọ́ láti máa bu ọlá náà fún mi ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé lórí ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì le è fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn.”