Deu 4:32-40

Deu 4:32-40 Bibeli Mimọ (YBCV)

Njẹ bère nisisiyi niti ọjọ́ igbãni, ti o ti mbẹ ṣaju rẹ, lati ọjọ́ ti Ọlọrun ti dá enia sori ilẹ, ki o si bère lati ìha ọrun kini dé ìha keji, bi irú nkan bi ohun nla yi wà rí, tabi bi a gburó irú rẹ̀ rí? Awọn enia kan ha gbọ́ ohùn Ọlọrun rí ki o ma bá wọn sọ̀rọ lati ãrin iná wá, bi iwọ ti gbọ́, ti o si wà lãye? Tabi Ọlọrun ha dán a wò rí lati lọ mú orilẹ-ède kan fun ara rẹ̀ lati ãrin orilẹ-ède miran wá, nipa idanwò, nipa àmi, ati nipa iṣẹ-iyanu, ati nipa ogun, ati nipa ọwọ́ agbara, ati nipa ninà apa, ati nipa ẹ̀ru nla, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun nyin ṣe fun nyin ni Egipti ni oju nyin? Iwọ li a fihàn, ki iwọ ki o le mọ̀ pe OLUWA on li Ọlọrun; kò sí ẹlomiran lẹhin rẹ̀. O mu ọ gbọ́ ohùn rẹ̀ lati ọrun wá, ki o le kọ́ ọ: ati lori ilẹ aiye o fi iná nla rẹ̀ hàn ọ; iwọ si gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ lati ãrin iná wá. Ati nitoriti o fẹ́ awọn baba rẹ, nitorina li o ṣe yàn irú-ọmọ wọn lẹhin wọn, o si fi agbara nla rẹ̀ mú ọ lati Egipti jade wá li oju rẹ̀; Lati lé awọn orilẹ-ède jade kuro niwaju rẹ, ti o tobi, ti o si lagbara jù ọ lọ, lati mú ọ wọle, lati fi ilẹ wọn fun ọ ni iní, bi o ti ri li oni yi. Nitorina ki iwọ ki o mọ̀ li oni, ki o si rò li ọkàn rẹ pe, OLUWA on li Ọlọrun loke ọrun, ati lori ilẹ nisalẹ: kò sí ẹlomiran. Nitorina ki iwọ ki o pa ìlana rẹ̀ mọ́, ati ofin rẹ̀, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o le dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ lori ilẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lailai.

Deu 4:32-40 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ lọ wádìí wò bí ó bá ṣẹlẹ̀ rí kí wọ́n tó bí yín, láti ọjọ́ tí Ọlọrun ti dá eniyan, ẹ wádìí káàkiri jákèjádò gbogbo àgbáyé bóyá irú nǹkan ńlá báyìí ṣẹlẹ̀ rí, tabi wọ́n pa á nítàn rí. Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kan gbọ́ kí oriṣa kan sọ̀rọ̀ láti ààrin gbùngbùn iná rí, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì tún wà láàyè? Tabi pé, oriṣa kan ti dìde rí, tí ó gbìdánwò àtifi ipá gba orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹlu àmì rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu, ati ogun, ati agbára ati àwọn nǹkan tí ó bani lẹ́rù, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ojú yín rí i tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe fun yín ní Ijipti? OLUWA fi èyí hàn yín, kí ẹ lè mọ̀ pé òun ni Ọlọrun, ati pé kò sí Ọlọrun mìíràn àfi òun nìkan. Ó mú kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, kí ó lè kọ yín; ó sì mú kí ẹ rí iná ńlá rẹ̀ láyé, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láàrin iná náà. Ìdí tí ó fi ṣe èyí ni pé, ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọmọ ọmọ wọn; ó fi agbára ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ó sì wà pẹlu yín. Ó lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ kúrò fun yín, kí ó baà lè ko yín wọlé kí ó sì fun yín ní ilẹ̀ wọn, kí ẹ sì jogún rẹ̀ bí ó ti wà lónìí. Kí ẹ mọ̀ lónìí, kí ó sì da yín lójú pé, OLUWA ni Ọlọrun; kò sí ọlọrun mìíràn mọ́ ní ọ̀run ati ní ayé. Nítorí náà, ẹ máa pa àwọn ìlànà ati òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, kí ó lè dára fun yín, ati fún àwọn ọmọ yín; kí ẹ lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, títí lae.”

Deu 4:32-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ béèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ béèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì. Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkí báyìí: ti ṣẹlẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí? Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè? Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀-èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnrarẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ ààmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína apá, àti nípa ẹ̀rù ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí OLúWA Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Ejibiti ní ojú ẹ̀yin tìkára yín? A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé OLúWA ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀. Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín. Ní ayé, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárín iná wá, torí pé ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan àwọn ọmọ wọn ní ipò lẹ́yìn wọn. Nípa ìwà láààyè àti nípa agbára ńlá rẹ̀ ni ó fi mú un yín kúrò ní Ejibiti. Láti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tóbi tí ó sì lágbára níwájú yín; láti le è mú un yín wá sí ilẹ̀ wọn kí ẹ lè jogún rẹ̀ bí ó ti rí lónìí. Ẹ gbà kí ẹ sì fi sọ́kàn lónìí pé OLúWA ni Ọlọ́run lókè ọ̀run lọ́hùn ún àti ní ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ níhìn-ín. Kò sí òmíràn mọ́. Ẹ pa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ tí mo ń fún un yín lónìí; kí ó ba à le è yẹ yín, kí ẹ̀yin sì le è pẹ́ ní ilẹ̀ tí OLúWA Ọlọ́run yín fún un yín ní gbogbo ìgbà.