Deu 34:1-12

Deu 34:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)

MOSE si gòke lati pẹtẹlẹ̀ Moabu lọ si òke Nebo, si ori Pisga, ti o dojukọ Jeriko. OLUWA si fi gbogbo ilẹ Gileadi dé Dani hàn a; Ati gbogbo Naftali, ati ilẹ Efraimu, ati ti Manasse, ati gbogbo ilẹ Juda, dé okun ìwọ-õrùn; Ati gusù, ati pẹtẹlẹ̀ afonifoji Jeriko, ilu ọlọpẹ dé Soari. OLUWA si wi fun u pe, Eyi ni ilẹ ti mo bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Emi o fi i fun irú-ọmọ rẹ: emi mu ọ fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ ki yio rekọja lọ sibẹ̀. Bẹ̃ni Mose iranṣẹ OLUWA kú nibẹ̀ ni ilẹ Moabu, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA. O si sin i ninu afonifoji ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Beti-peori; ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o mọ̀ iboji rẹ̀ titi di oni-oloni. Mose si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún nigbati o kú: oju rẹ̀ kò ṣe baìbai, bẹ̃li agbara rẹ̀ kò dinku. Awọn ọmọ Israeli si sọkun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu li ọgbọ̀n ọjọ́: bẹ̃li ọjọ́ ẹkún ati ọ̀fọ Mose pari. Joṣua ọmọ Nuni si kún fun ẹmi ọgbọ́n; nitoripe Mose ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé e lori: awọn ọmọ Israeli si gbà tirẹ̀ gbọ́, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose. Wolĩ kan kò si hù mọ́ ni Israeli bi Mose, ẹniti OLUWA mọ̀ li ojukoju, Ni gbogbo iṣẹ-àmi ati iṣẹ-iyanu, ti OLUWA rán a lati ṣe ni ilẹ Egipti, si Farao, ati si gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati si gbogbo ilẹ rẹ̀; Ati ni gbogbo ọwọ́ agbara, ati ni gbogbo ẹ̀ru nla ti Mose fihàn li oju gbogbo Israeli.

Deu 34:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Mose gbéra láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ó gun orí òkè Nebo lọ títí dé ṣóńṣó òkè Pisiga, tí ó wà ní òdìkejì Jẹriko. OLUWA sì fi gbogbo ilẹ̀ náà hàn án láti Gileadi lọ, títí dé Dani, gbogbo ilẹ̀ Nafutali, ilẹ̀ Efuraimu, ilẹ̀ Manase, ati gbogbo ilẹ̀ Juda, títí dé etí òkun ìwọ̀ oòrùn, ilẹ̀ Nẹgẹbu ni apá gúsù ati gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó wà ní àfonífojì Jẹriko, ìlú tí ó kún fún ọ̀pẹ, títí dé ilẹ̀ Soari. OLUWA wí fún un pé, “Ilẹ̀ tí mo búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé, n óo fi fún àwọn arọmọdọmọ wọn nìyí, mo jẹ́ kí o rí i, ṣugbọn o kò ní dé ibẹ̀.” Mose iranṣẹ OLUWA kú ní ilẹ̀ Moabu gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA. OLUWA sin ín sí àfonífojì ilẹ̀ Moabu tí ó dojú kọ Betipeori, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò mọ ibojì rẹ̀ títí di òní olónìí. Mose jẹ́ ẹni ọgọfa (120) ọdún nígbà tí ó kú, ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù. Àwọn ọmọ Israẹli ṣọ̀fọ̀ Mose fún ọgbọ̀n ọjọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, wọ́n sì parí ṣíṣe òkú rẹ̀. Joṣua ọmọ Nuni kún fún ọgbọ́n nítorí pé Mose ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, nítorí náà àwọn ọmọ Israẹli ń gbọ́ tirẹ̀, wọ́n sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose. Láti ìgbà náà, kò tíì sí wolii mìíràn ní ilẹ̀ Israẹli tí ó dàbí Mose, ẹni tí Ọlọrun bá sọ̀rọ̀ lojukooju. Kò sì sí ẹlòmíràn tí OLUWA rán láti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lára Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, ní ilẹ̀ Ijipti. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí wolii mìíràn tí ó ní agbára ńlá tabi tí ó ṣe àwọn ohun tí ó bani lẹ́rù bí Mose ti ṣe lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

Deu 34:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Mose gun òkè Nebo láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu sí orí Pisga tí ó dojúkọ Jeriko. Níbẹ̀ ni OLúWA ti fi gbogbo ilẹ̀ hàn án láti Gileadi dé Dani, gbogbo Naftali, ilẹ̀ Efraimu àti Manase, gbogbo ilẹ̀ Juda títí dé Òkun ìwọ̀-oòrùn, gúúsù àti gbogbo Àfonífojì Jeriko, ìlú ọlọ́pẹ dé Soari. Nígbà náà ní OLúWA sọ fún un pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí mo ṣèlérí lórí ìbúra fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu nígbà tí mo wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’ Mo ti jẹ́ kí o rí i pẹ̀lú ojú rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò dé bẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Mose ìránṣẹ́ OLúWA kú ní ilẹ̀ Moabu, bí OLúWA ti wí. Ó sì sin ín nínú àfonífojì ní ilẹ̀ Moabu, ní òdìkejì Beti-Peori, ṣùgbọ́n títí di òní yìí, kò sí ẹnìkan tí ó mọ ibi tí ibojì i rẹ̀ wà. Mose jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà tí ó kú, síbẹ̀ ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù. Àwọn ọmọ Israẹli sọkún un Mose ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ọgbọ̀n ọjọ́ títí di ìgbà tí ọjọ́ ẹkún àti ọ̀fọ̀ Mose parí. Joṣua ọmọ Nuni kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n nítorí Mose ti gbọ́wọ́ ọ rẹ̀ lé e lórí. Àwọn ọmọ Israẹli sì fetí sí i wọ́n sì ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Mose. Láti ìgbà náà kò sì sí wòlíì tí ó dìde ní Israẹli bí i Mose, ẹni tí OLúWA mọ̀ lójúkojú, tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu tí OLúWA rán an láti lọ ṣe ní Ejibiti sí Farao àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà. Nítorí kò sí ẹni tí ó tí ì fi gbogbo ọ̀rọ̀ agbára hàn, tàbí ṣe gbogbo ẹ̀rù ńlá tí Mose fihàn ní ojú gbogbo Israẹli.