Deu 33:1-17

Deu 33:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

EYI si ni ire, ti Mose enia Ọlọrun su fun awọn ọmọ Israeli ki o to kú. O si wipe, OLUWA ti Sinai wá, o si yọ si wọn lati Seiri wá; o tàn imọlẹ jade lati òke Parani wá, o ti ọdọ ẹgbẹgbãrun awọn mimọ́ wá: lati ọwọ́ ọtún rẹ̀ li ofin kan amubĩná ti jade fun wọn wá. Nitõtọ, o fẹ́ awọn enia na; gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀ wà li ọwọ́ rẹ. Nwọn si joko li ẹsẹ̀ rẹ; olukuluku ni yio gbà ninu ọ̀rọ rẹ. Mose fi ofin kan lelẹ li aṣẹ fun wa, iní ti ijọ enia Jakobu. O si jẹ́ ọba ni Jeṣuruni, nigbati olori awọn enia, awọn ẹ̀ya Israeli pejọ pọ̀. Ki Reubeni ki o yè, ki o máṣe kú; ki enia rẹ̀ ki o máṣe mọniwọn. Eyi si ni ti Judah: o si wipe, OLUWA, gbọ́ ohùn Judah, ki o si mú u tọ̀ awọn enia rẹ̀ wá: ki ọwọ́ rẹ̀ ki o to fun u; ki iwọ ki o si ṣe iranlọwọ fun u lọwọ awọn ọtá rẹ̀. Ati niti Lefi o wipe, Jẹ ki Tummimu ati Urimu rẹ ki o wà pẹlu ẹni mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ danwò ni Massa, ati ẹniti iwọ bá jà li omi Meriba; Ẹniti o wi niti baba rẹ̀, ati niti iya rẹ̀ pe, Emi kò ri i; bẹ̃ni kò si jẹwọ awọn arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò si mọ̀ awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti nwọn kiyesi ọ̀rọ rẹ, nwọn si pa majẹmu rẹ mọ́. Nwọn o ma kọ́ Jakobu ni idajọ rẹ, ati Israeli li ofin rẹ: nwọn o ma mú turari wá siwaju rẹ, ati ọ̀tọtọ ẹbọ sisun sori pẹpẹ rẹ. OLUWA, busi ohun-iní rẹ̀, ki o si tẹwọgbà iṣẹ ọwọ́ rẹ̀: lù ẹgbẹ́ awọn ti o dide si i, ati ti awọn ti o korira rẹ̀, ki nwọn ki o máṣe dide mọ́. Ati niti Benjamini o wipe, Olufẹ OLUWA yio ma gbé li alafia lọdọ rẹ̀; on a ma bò o li ọjọ́ gbogbo, on a si ma gbé lãrin ejika rẹ̀. Ati niti Josefu o wipe, Ibukún OLUWA ni ilẹ rẹ̀, fun ohun iyebiye ọrun, fun ìri, ati fun ibú ti o ba nisalẹ, Ati fun eso iyebiye ti õrùn múwa, ati fun ohun iyebiye ti ndàgba li oṣoṣù, Ati fun ohun pàtaki okenla igbãni, ati fun ohun iyebiye òke aiyeraiye, Ati fun ohun iyebiye aiye ati ẹkún rẹ̀, ati fun ifẹ́ inurere ẹniti o gbé inu igbẹ́: jẹ ki ibukún ki o wá si ori Josefu, ati si atari ẹniti a yàsọtọ lãrin awọn arakunrin rẹ̀. Akọ́bi akọmalu rẹ̀, tirẹ̀ li ọlánla; iwo rẹ̀ iwo agbanrere ni: on ni yio fi tì awọn enia, gbogbo wọn, ani opin ilẹ: awọn si ni ẹgbẹgbãrun Efraimu, awọn si ni ẹgbẹgbẹrun Manasse.

Deu 33:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Ìre tí Mose eniyan Ọlọrun sú fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú nìyí. Ó ní: OLUWA wá láti orí òkè Sinai, ó yọ gẹ́gẹ́ bí oòrùn láti Edomu, ó ràn sórí àwọn eniyan rẹ̀ láti òkè Parani. Ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹgbaarun àwọn ẹni mímọ́, ó gbé iná tí ń jò lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Ọlọrun fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀, gbogbo àwọn tí a yà sọ́tọ̀ fún un wà lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí náà ni wọ́n ṣe ń tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀, tí wọ́n sì ń gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí Mose bá fún wa ní òfin, tí ó jẹ́ ohun ìní gbogbo eniyan Israẹli. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe di ọba ní Jeṣuruni, nígbà tí gbogbo àwọn olórí péjọ, àní, gbogbo àwọn olórí ninu ẹ̀yà Israẹli. Mose súre fún ẹ̀yà Reubẹni, ó ní: “Ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ni, kò ní parun, àwọn eniyan rẹ̀ kò ní dínkù.” Ó súre fún ẹ̀yà Juda pé: “OLUWA, gbọ́ igbe ẹ̀yà Juda, nígbà tí wọ́n bá pè fún ìrànwọ́, sì kó wọn pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wọn. Fi ọwọ́ ara rẹ jà fún wọn, sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ọ̀tá wọn.” Ó súre fún ẹ̀yà Lefi pé: “OLUWA, fún Lefi, ẹni tíí ṣe olódodo, ní Tumimu ati Urimu rẹ; Lefi, tí o dánwò ní Masa, tí o sì bá jà níbi odò tí ó wà ní Meriba; àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn kò ka òbí àwọn sí, ju ìwọ OLUWA lọ; wọ́n kọ àwọn arakunrin wọn sílẹ̀, wọ́n sì ṣá àwọn ọmọ wọn tì. Nítorí pé wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, wọ́n sì ń pa majẹmu rẹ mọ́. Wọn óo kọ́ ilé Jakọbu ní ìlànà rẹ, wọn óo sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli ní òfin rẹ. Àwọn ni wọn óo máa sun turari níbi ẹbọ rẹ, wọn óo sì máa rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ rẹ. OLUWA, bukun àwọn ohun ìní wọn, sì jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wọn jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lójú rẹ, Fọ́ egungun itan àwọn ọ̀tá wọn, tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́, kí àwọn tí wọ́n bá kórìíra wọn má sì lè gbérí mọ́.” Ó súre fún ẹ̀yà Bẹnjamini pé: “Bẹnjamini, ẹ̀yà tí OLUWA fẹ́ràn tí ó sì ń dáàbò bò, OLUWA ń ṣọ́ wọn nígbà gbogbo, ó sì ń gbé ààrin wọn.” Ó súre fún ẹ̀yà Josẹfu pé: “Kí OLUWA rọ òjò ibukun sórí ilẹ̀ wọn, kí ó sì bu omi rin ín láti abẹ́ ilẹ̀ wá. Kí OLUWA pèsè ọpọlọpọ èso sórí ilẹ̀ wọn, kí ó sì kún fún àwọn èso tí ó dára jùlọ láti ìgbà dé ìgbà. Kí àwọn òkè ńláńlá àtijọ́ so ọpọlọpọ èso dáradára, kí ọpọlọpọ èso sì bo àwọn òkè kéékèèké. Kí ilẹ̀ wọn kún fún oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ó dára, pẹlu ibukun láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ń gbé inú pápá tí ń jó. Kí ó wá sórí Josẹfu, àní, sórí ẹni tó jẹ́ aṣiwaju fún àwọn arakunrin rẹ̀. Àkọ́bí rẹ̀ lágbára bí akọ mààlúù, Ìwo rẹ̀ sì dàbí ìwo mààlúù tí ó lágbára, tí yóo fi máa ti àwọn orílẹ̀-èdè títí dé òpin ayé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹgbẹẹgbaarun àwọn ọmọ Efuraimu, ati ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Manase.”

Deu 33:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni ìbùkún tí Mose ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú. Ó sì wí pé: “OLúWA ti Sinai wá, ó sì yọ sí wọn láti Seiri wá ó sì tàn án jáde láti òkè Parani wá. Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn-ún àwọn mímọ́ wá láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan a mú bí iná ti jáde fún wọn wá. Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀. Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀, òfin tí Mose fi fún wa, ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu. Òun ni ọba lórí Jeṣuruni ní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọpọ̀, pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Israẹli. “Jẹ́ kí Reubeni yè kí ó má ṣe kú, tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.” Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Juda: “OLúWA gbọ́ ohùn Juda kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá. Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un, kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!” Ní ti Lefi ó wí pé: “Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ. Ẹni tí ó dánwò ní Massa, ìwọ bá jà ní omi Meriba. Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé, ‘Èmi kò buyì fún wọn.’ Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́. Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀ àti Israẹli ní òfin rẹ̀. Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀ àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀. Bùsi ohun ìní rẹ̀, OLúWA, kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i; àwọn tí ó kórìíra rẹ̀, kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.” Ní ti Benjamini ó wí pé: “Jẹ́ kí olùfẹ́ OLúWA máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́, ẹni tí OLúWA fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.” Ní ti Josẹfu ó wí pé: “Kí OLúWA bùkún ilẹ̀ rẹ, fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀; àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù; pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé; Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀ àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó. Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Josẹfu, lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀. Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù; ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni. Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè, pàápàá títí dé òpin ayé. Àwọn ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún (10,000) Efraimu, àwọn sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún (1,000) Manase.”