Deu 32:46-47
Deu 32:46-47 Yoruba Bible (YCE)
ó ní, “Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ba yín sọ lónìí sọ́kàn, kí ẹ sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ yín, kí wọ́n lè pa gbogbo òfin wọnyi mọ́ lẹ́sẹẹsẹ. Nítorí pé kìí ṣe nǹkan yẹpẹrẹ ni, òun ni ẹ̀mí yín. Bí ẹ bá pa á mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá Jọdani lọ gbà.”
Deu 32:46-47 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun wọn pe, Ẹ gbé ọkàn nyin lé gbogbo ọ̀rọ ti mo sọ lãrin nyin li oni; ti ẹnyin o palaṣẹ fun awọn ọmọ nyin lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi. Nitoripe ki iṣe ohun asan fun nyin; nitoripe ìye nyin ni, ati nipa eyi li ẹnyin o mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ na, nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a.
Deu 32:46-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ láàrín yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́rọ̀ àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí. Wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jordani lọ láti gbà.”