Deu 32:45-52
Deu 32:45-52 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose si pari sisọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo Israeli: O si wi fun wọn pe, Ẹ gbé ọkàn nyin lé gbogbo ọ̀rọ ti mo sọ lãrin nyin li oni; ti ẹnyin o palaṣẹ fun awọn ọmọ nyin lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi. Nitoripe ki iṣe ohun asan fun nyin; nitoripe ìye nyin ni, ati nipa eyi li ẹnyin o mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ na, nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a. OLUWA si sọ fun Mose li ọjọ́ na gan, wipe, Gùn òke Abarimu yi lọ, si òke Nebo, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Jeriko; ki o si wò ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli ni iní. Ki o si kú lori òke na, nibiti iwọ ngùn lọ, ki a si kó ọ jọ sọdọ awọn enia rẹ; bi Aaroni arakunrin rẹ ti kú li òke Horu, ti a si kó o jọ sọdọ awọn enia rẹ̀: Nitoriti ẹnyin ṣẹ̀ si mi lãrin awọn ọmọ Israeli ni ibi omi Meriba-Kadeṣi, li aginjù Sini; nitoriti ẹnyin kò yà mi simimọ́ lãrin awọn ọmọ Israeli. Ṣugbọn iwọ o ri ilẹ na niwaju rẹ; ṣugbọn iwọ ki yio lọ sibẹ̀, si ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli.
Deu 32:45-52 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Mose bá àwọn ọmọ Israẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi tán, ó ní, “Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ba yín sọ lónìí sọ́kàn, kí ẹ sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ yín, kí wọ́n lè pa gbogbo òfin wọnyi mọ́ lẹ́sẹẹsẹ. Nítorí pé kìí ṣe nǹkan yẹpẹrẹ ni, òun ni ẹ̀mí yín. Bí ẹ bá pa á mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń rékọjá Jọdani lọ gbà.” OLUWA sọ fún Mose ní ọjọ́ náà gan-an pé, “Lọ sí òkè Abarimu tí ó dojú kọ ìlú Jẹriko, ní ilẹ̀ Moabu. Gun orí òkè Nebo lọ, kí o sì wo gbogbo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn eniyan Israẹli. Orí òkè Nebo yìí ni o óo kú sí, bí Aaroni arakunrin rẹ ṣe kú lórí òkè Hori. Nítorí pé, ẹ̀yin mejeeji ni ẹ kò hùwà òtítọ́ sí mi láàrin àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí ẹ wà ní odò Meriba Kadeṣi, ní aṣálẹ̀ Sini. Ẹ tàbùkù mi lójú gbogbo àwọn eniyan, ẹ kò bọ̀wọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ níwájú àwọn eniyan náà. Nítorí náà, o óo fi ojú rí ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹsẹ̀ rẹ kò ní tẹ ilẹ̀ tí n ó fún àwọn eniyan Israẹli.”
Deu 32:45-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Mose parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Israẹli. Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ láàrín yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́rọ̀ àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí. Wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jordani lọ láti gbà.” Ní ọjọ́ kan náà, OLúWA sọ fún Mose pé, “Gòkè lọ sí Abarimu sí òkè Nebo ní Moabu, tí ó kọjú sí Jeriko, kí o sì wo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Israẹli, bí ìní i wọn. Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kùú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Aaroni ti kú ní orí òkè Hori tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀. Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrín àwọn ọmọ Israẹli ní ibi omi Meriba Kadeṣi ní aginjù Sini àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrín àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí náà, ìwọ yóò rí ilẹ̀ náà ní ọ̀kánkán, o kì yóò wọ inú rẹ̀ ilẹ̀ ti mo ti fi fún àwọn ọmọ Israẹli.”