Deu 31:14-29

Deu 31:14-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, ọjọ́ rẹ sunmọ-etile ti iwọ o kú: pè Joṣua, ki ẹ si fara nyin hàn ninu agọ́ ajọ, ki emi ki o le fi aṣẹ lé e lọwọ. Mose ati Joṣua si lọ, nwọn si fara wọn hàn ninu agọ́ ajọ. OLUWA si yọ si wọn ninu agọ́ na ninu ọwọ̀n awọsanma: ọwọ̀n awọsanma na si duro loke ẹnu-ọ̀na agọ́ na. OLUWA si sọ fun Mose pe, Kiyesi i, iwọ o sùn pẹlu awọn baba rẹ; awọn enia yi yio si dide, nwọn o si ma ṣe àgbere tọ̀ awọn oriṣa ilẹ na lẹhin, nibiti nwọn nlọ lati gbé inu wọn, nwọn o si kọ̀ mi silẹ, nwọn o si dà majẹmu mi ti mo bá wọn dá. Nigbana ni ibinu mi yio rú si wọn li ọjọ́ na, emi o si kọ̀ wọn silẹ, emi o si pa oju mi mọ́ kuro lara wọn, a o si jẹ wọn run, ati ibi pupọ̀ ati iyọnu ni yio bá wọn; tobẹ̃ ti nwọn o si wi li ọjọ́ na pe, Kò ha jẹ́ pe nitoriti Ọlọrun wa kò sí lãrin wa ni ibi wọnyi ṣe bá wa? Emi o fi oju mi pamọ́ patapata li ọjọ́ na, nitori gbogbo ìwabuburu ti nwọn o ti hù, nitori nwọn yipada si oriṣa. Njẹ nisisiyi, kọwe orin yi fun ara nyin, ki ẹ fi kọ́ awọn ọmọ Israeli: fi i si wọn li ẹnu, ki orin yi ki o le ma jẹ́ ẹrí fun mi si awọn ọmọ Israeli. Nitoripe nigbati emi ba mú wọn wá si ilẹ na, ti mo bura fun awọn baba wọn, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin; ti nwọn ba si jẹ ajẹyo tán, ti nwọn si sanra; nigbana ni nwọn o yipada si oriṣa, nwọn a si ma sìn wọn, nwọn a si kẹ́gan mi, nwọn a si dà majẹmu mi. Yio si ṣe, nigbati ibi pupọ̀ ati iyọnu ba bá wọn, ki orin yi ki o jẹri tì wọn bi ẹlẹri; nitoripe a ki yio gbagbé rẹ̀ lati ẹnu awọn ọmọ wọn: nitori mo mọ̀ ìro inu wọn, ti nwọn nrò, ani nisisiyi, ki emi ki o to mú wọn wá sinu ilẹ na ti mo bura si. Nitorina ni Mose ṣe kọwe orin yi li ọjọ́ na gan, o si fi kọ́ awọn ọmọ Israeli. O si paṣẹ fun Joṣua ọmọ Nuni, o si wipe, Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio mú awọn ọmọ Israeli lọ sinu ilẹ na ti mo bura fun wọn: Emi o si wà pẹlu rẹ. O si ṣe, nigbati Mose pari kikọ ọ̀rọ ofin yi tán sinu iwé, titi nwọn fi pari, Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, ti nrù apoti majẹmu OLUWA, wipe, Gbà iwé ofin yi, ki o si fi i sapakan apoti majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o ma wà nibẹ̀ fun ẹrí si ọ. Nitoripe mo mọ̀ ọ̀tẹ rẹ, ati lile ọrùn rẹ: kiyesi i, nigbati emi wà lãye sibẹ̀ pẹlu nyin li oni, ọlọtẹ̀ li ẹnyin ti nṣe si OLUWA; melomelo si ni lẹhin ikú mi? Pè gbogbo awọn àgba ẹ̀ya nyin jọ sọdọ mi, ati awọn ijoye nyin, ki emi ki o le sọ ọ̀rọ wọnyi li etí wọn ki emi ki o si pè ọrun ati aiye jẹri tì wọn. Nitori mo mọ̀ pe lẹhin ikú mi ẹnyin o bà ara nyin jẹ́ patapata, ati pe ẹnyin o yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin; ibi yio si bá nyin li ọjọ́ ikẹhin; nitoriti ẹnyin o ma ṣe buburu li oju OLUWA, lati fi iṣẹ ọwọ́ nyin mu u binu.

Deu 31:14-29 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Àkókò ń tó bọ̀ tí o óo kú, pe Joṣua, kí ẹ̀yin mejeeji wá sinu àgọ́ àjọ kí n lè fi ohun tí yóo ṣe lé e lọ́wọ́.” Mose ati Joṣua bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ. OLUWA fi ara hàn wọ́n ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu ninu àgọ́ náà. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu náà wà ní ẹ̀bá ẹnu ọ̀nà àgọ́. OLUWA tún sọ fún Mose pé, “Ọjọ́ àtisùn rẹ kù sí dẹ̀dẹ̀. Àwọn eniyan wọnyi yóo lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn ará ilẹ̀ náà ń bọ. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu tí mo bá wọn dá. Inú mi yóo ru sí wọn ní ọjọ́ náà, èmi náà óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀, n óo mú ojú mi kúrò lára wọn, n óo sì pa wọ́n run. Oríṣìíríṣìí ibi ati wahala ni yóo bá wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo máa wí ní ọjọ́ náà pé, ‘Ǹjẹ́ nítorí pé kò sí Ọlọrun wa láàrin wa kọ́ ni gbogbo ibi wọnyi fi dé bá wa?’ Láìṣe àní àní, n óo mú ojú kúrò lára wọn ní ọjọ́ náà, nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, nítorí pé wọ́n ti yipada, wọ́n sì ń bọ oriṣa. “Nítorí náà, kọ orin yìí sílẹ̀ nisinsinyii kí o sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, kí orin náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi lọ́dọ̀ wọn. Nítorí pé, nígbà tí mo bá kó wọn wọ ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, tí mo ti búra pé n óo fún àwọn baba wọn; nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí wọ́n yó tán, tí wọ́n sì sanra, wọn óo yipada sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọn óo sì máa bọ wọ́n. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu mi. Nígbà tí ọpọlọpọ ibi ati wahala bá dé bá wọn, orin yìí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí fún wọn (nítorí pé arọmọdọmọ wọn yóo máa kọ ọ́, wọn kò sì ní gbàgbé rẹ̀); nítorí pé mo mọ ète tí wọn ń pa, kí ó tilẹ̀ tó di pé mo mú wọn wọ ilẹ̀ tí mo búra láti fún wọn.” Mose bá kọ orin yìí ní ọjọ́ náà-gan an, ó sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli. OLUWA fi iṣẹ́ lé Joṣua ọmọ Nuni lọ́wọ́, ó ní, “Múra gírí kí o sì mú ọkàn gidigidi, nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn ọmọ Israẹli wọ ilẹ̀ tí mo ti búra láti fún wọn. N óo wà pẹlu rẹ.” Nígbà tí Mose kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé òfin yìí tán patapata, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA, ó ní, “Ẹ fi ìwé òfin yìí sí ẹ̀gbẹ́ àpótí majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, kí ó wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pẹlu yín; nítorí mo mọ̀ pé ọlọ̀tẹ̀ ati olóríkunkun ni yín; nígbà tí mo wà láàyè pẹlu yín lónìí, ẹ̀ ń ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ìgbà tí mo bá kú tán. Ẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ẹ̀yà yín wá sọ́dọ̀ mi, ati gbogbo àwọn olórí ninu yín, kí àwọn náà lè máa gbọ́ bí mo ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ sì pe ọ̀run ati ayé láti ṣe ẹlẹ́rìí wọn. Nítorí mo mọ̀ dájú pé gẹ́rẹ́ tí mo bá kú tán, ìṣekúṣe ni ẹ óo máa ṣe, ẹ óo sì yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pa láṣẹ fun yín, ibi ni yóo sì ba yín ní ọjọ́ iwájú, nítorí pé ẹ óo ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. Iṣẹ́ ọwọ́ yín yóo sì mú un bínú.”

Deu 31:14-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé, “Ọjọ́ ikú rẹ ti súnmọ́ etílé báyìí. Pe Joṣua kí ẹ sì fi ara yín hàn nínú àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti fi àṣẹ fún un.” Nígbà náà ni Mose àti Joṣua wá, wọ́n sì fi ara wọn hàn níbi àgọ́ àjọ. Nígbà náà ni OLúWA farahàn níbi àgọ́ ní ọ̀wọ́ àwọsánmọ̀, àwọsánmọ̀ náà sì dúró sókè ẹnu-ọ̀nà àgọ́. OLúWA sì sọ fún Mose pé: “Ìwọ ń lọ sinmi pẹ̀lú àwọn baba à rẹ, àwọn wọ̀nyí yóò sì ṣe àgbèrè ara wọn sí ọlọ́run àjèjì ilẹ̀ tí wọn ń wọ̀ lọ láìpẹ́. Wọn yóò kọ̀ mí sílẹ̀ wọn yóò sì da májẹ̀mú tí mo bá wọn dá. Ní ọjọ́ náà ni èmi yóò bínú sí wọn èmi yóò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀; èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò fún wọn, wọn yóò sì parun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjálù àti ìṣòro yóò wá sórí wọn, àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ìpọ́njú wọ̀nyí kò wá sórí i wa nítorí Ọlọ́run wa kò sí pẹ̀lú u wa?’ Èmi yóò sì pa ojú mi mọ́ dájúdájú ní ọjọ́ náà nítorí i gbogbo ìwà búburú wọn ní yíyípadà sí ọlọ́run mìíràn. “Ní báyìí kọ ọ́ kalẹ̀ fúnra à rẹ orin yìí kí o sì kọ ọ́ sí Israẹli kí o sì jẹ́ kí wọn kọ ọ́ kí ó lè jẹ́ ẹ̀rí ì mi sí wọn. Nígbà tí mo ti mú wọn wá sí ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin, ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí ní ìbúra fún àwọn baba ńlá wọn, àti nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí ó sì tẹ́ wọn lọ́rùn, tí wọ́n sì gbilẹ̀, wọn yóò yí padà sí ọlọ́run mìíràn wọn yóò sì sìn wọ́n, wọn yóò kọ̀ mí sílẹ̀, wọn yóò sì da májẹ̀mú mi. Àti nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú àti ìṣòro bá wá sórí i wọn, orin yìí yóò jẹ́ ẹ̀rí sí wọn, nítorí kò ní di ìgbàgbé fún àwọn ọmọ wọn. Mo mọ̀ ohun tí wọ́n ní inú dídùn sí láti ṣe, pàápàá kí èmi tó mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo ṣe ìlérí fún wọn lórí ìbúra.” Nígbà náà ni Mose kọ orin yìí kalẹ̀ ní ọjọ́ náà ó sì kọ ọ́ sí Israẹli. OLúWA sì fún Joṣua ọmọ Nuni ní àṣẹ yìí: “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí ìwọ yóò mú Israẹli wá sí ilẹ̀ tí mo ṣèlérí fún wọn lórí ìbúra, èmi fúnra à mi yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.” Lẹ́yìn ìgbà tí Mose ti parí i kíkọ ọ̀rọ̀ òfin yìí sínú ìwé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó sì fi àṣẹ yìí fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ń gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA: “Gba ìwé òfin yìí kí o sì fi sí ẹ̀gbẹ́ àpótí ẹ̀rí OLúWA Ọlọ́run rẹ. Níbẹ̀ ni yóò wà bí ẹ̀rí sí ọ. Nítorí mo mọ irú ọlọ̀tẹ̀ àti ọlọ́rùn líle tí ẹ jẹ́. Bí o bá ṣe ọlọ̀tẹ̀ sí OLúWA nígbà tí mo pàpà wà láyé Pẹ̀lú yín, báwo ní ẹ ó ti ṣe ọlọ̀tẹ̀ tó nígbà tí mo bá kú tán! Ẹ péjọpọ̀ síwájú mi gbogbo àgbà ẹ̀yà yín àti àwọn aláṣẹ yín, kí èmi lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí etí ìgbọ́ ọ́ wọn. Nítorí tí mo mọ̀ pé lẹ́yìn ikú mi, ó dájú pé ìwọ yóò padà di ìbàjẹ́ pátápátá, ẹ ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pàṣẹ fún un yín. Ní ọjọ́ tó ń bọ̀, ìpọ́njú yóò sọ̀kalẹ̀ sórí i yín nítorí ẹ̀yin yóò ṣe búburú níwájú OLúWA ẹ ó sì mú u bínú nípa ohun tí ọwọ́ yín ti ṣe.”