Deu 30:17-18
Deu 30:17-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi àiya rẹ ba pada, ti iwọ kò ba si gbọ́, ṣugbọn ti iwọ di ẹni fifà lọ, ti iwọ si mbọ oriṣa, ti iwọ si nsìn wọn; Emi sọ fun nyin li oni, pe ṣiṣegbé li ẹnyin o ṣegbé; ẹnyin ki yio mu ọjọ́ nyin pẹ lori ilẹ, nibiti iwọ ngòke Jordani lọ lati gbà a.
Deu 30:17-18 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn bí ọkàn yín bá yipada, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ kí wọn fà yín lọ bọ àwọn oriṣa, tí ẹ sì ń sìn wọ́n, mo wí fun yín gbangba lónìí pé, ẹ óo parun. Ẹ kò ní pẹ́ rárá lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gòkè Jọdani lọ gbà, tí yóo sì di tiyín.
Deu 30:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n tí ọkàn an yín bá yí padà tí ìwọ kò sì ṣe ìgbọ́ràn, àti bí o bá fà, lọ láti foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn àti sìn wọ́n, èmi ń sọ fún un yín lónìí yìí pé ìwọ yóò parun láìsí àní àní. O kò ní í gbé pẹ́ ní ilẹ̀ tí ìwọ ń kọjá Jordani láti gbà àti láti ní.