Deu 30:1-6
Deu 30:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
YIO si ṣe, nigbati gbogbo nkan wọnyi ba dé bá ọ, ibukún ati egún, ti mo filelẹ niwaju rẹ, ti iwọ o ba si ranti ninu gbogbo orilẹ-ède, nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si, Ti iwọ ba si yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo; Nigbana ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio yi oko-ẹrú rẹ pada, yio si ṣãnu fun ọ, yio si pada, yio si kó ọ jọ kuro ninu gbogbo orilẹ-ède wọnni nibiti OLUWA Ọlọrun rẹ ti tu ọ ká si. Bi a ba si lé ẹni rẹ kan lọ si ìha opin ọrun, lati ibẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio kó ọ jọ, lati ibẹ̀ ni yio si mú ọ wá: OLUWA Ọlọrun rẹ yio si mú ọ wá sinu ilẹ na ti awọn baba rẹ ti ní, iwọ o si ní i; on o si ṣe ọ li ore, yio si mu ọ bisi i jù awọn baba rẹ lọ. OLUWA Ọlọrun rẹ yio si kọ àiya rẹ nilà, ati àiya irú-ọmọ rẹ, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo, ki iwọ ki o le yè.
Deu 30:1-6 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí gbogbo àwọn ibukun tabi ègún tí mo gbé kalẹ̀ níwájú yín lónìí bá ṣẹ mọ́ yín lára, tí ẹ bá dé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí, tí ẹ bá ranti anfaani tí ẹ ti sọnù, tí ẹ bá yipada sí OLUWA Ọlọrun yín, ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín; tí ẹ bá tún ń gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ sì ń fi tọkàntọkàn tẹ̀lé gbogbo òfin tí mo ṣe fun yín lónìí, OLUWA Ọlọrun yín yóo dá ibukun yín pada, yóo ṣàánú yín, yóo sì tún ko yín pada láti ààrin àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo tí ó fọn yín ká sí. Ibi yòówù tí OLUWA bá fọn yín ká sí ninu ayé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ òpin ayé, OLUWA yóo wa yín rí, yóo sì ko yín jọ. OLUWA Ọlọrun yín yóo tún da yín pada sí ilẹ̀ àwọn baba yín, ilẹ̀ náà yóo tún pada di tiyín, OLUWA yóo mú kí ó dára fun yín, yóo mú kí ẹ pọ̀ ju àwọn baba yín lọ. OLUWA Ọlọrun yín yóo fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín ní ẹ̀mí ìgbọràn tí ó fi jẹ́ pé ẹ óo fẹ́ràn rẹ̀ tọkàntọkàn, ẹ óo sì wà láàyè.
Deu 30:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí gbogbo ìbùkún àti ègún wọ̀nyí tí mo ti gbé kalẹ̀ síwájú u yín bá wá sórí i yín àti tí o bá mú wọn sí àyà rẹ níbikíbi tí OLúWA Ọlọ́run rẹ bá tú ọ ká sí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, àti nígbà tí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ bá yípadà sí OLúWA Ọlọ́run rẹ tí o sì gbọ́rọ̀ sí pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un yín lónìí. Nígbà náà ni OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò mú ohun ìní rẹ bọ̀ sípò yóò sì ṣàánú fún ọ, yóò sì tún ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè níbi tí ó ti fọ́n yín ká sí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ẹni rẹ kan sí ilẹ̀ tí ó jìnnà jù lábẹ́ ọ̀run, láti ibẹ̀ OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò ṣà yín jọ yóò sì tún mú u yín padà. Yóò mú ọ wá sí ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn baba yín, ìwọ yóò sì mú ìní níbẹ̀. OLúWA yóò mú ọ wà ní àlàáfíà kíkún, yóò mú ọ pọ̀ sí i ju àwọn baba yín lọ. OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò kọ ọkàn rẹ ní ilà àti ọkàn àwọn ọmọ yín, nítorí kí o lè fẹ́ ẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, àti ayé rẹ.