Deu 28:7-9
Deu 28:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje. OLúWA yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ rẹ lé. OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ. OLúWA yóò fi ọ́ múlẹ̀ bí ènìyàn mímọ́, bí ó ti ṣe ìlérí fún ọ lórí ìbúra, bí o bá pa àṣẹ OLúWA Ọlọ́run rẹ mọ́ tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
Deu 28:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA yio mu awọn ọtá rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlù niwaju rẹ: nwọn o jade si ọ li ọ̀na kan, nwọn o si sá niwaju rẹ li ọ̀na meje. OLUWA yio paṣẹ ibukún sori rẹ ninu aká rẹ, ati ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé; on o si busi i fun ọ ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. OLUWA yio fi idi rẹ kalẹ li enia mimọ́ fun ara rẹ̀, bi o ti bura fun ọ, bi iwọ ba pa aṣẹ ỌLUWA Ọlọrun rẹ mọ́, ti iwọ si rìn li ọ̀na rẹ̀.
Deu 28:7-9 Yoruba Bible (YCE)
“Yóo bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá tí ó bá dìde sí ọ. Bí wọ́n bá gba ọ̀nà kan dìde sí ọ, yẹ́lẹyẹ̀lẹ ni wọn óo fọ́nká nígbà tí wọn bá ń sálọ fún ọ. “OLUWA yóo bukun ìkórè inú àká rẹ, ati gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé. OLUWA Ọlọrun rẹ yóo bukun ọ ní ilẹ̀ tí ó fún ọ. “OLUWA yóo ṣe ọ́ ní eniyan rẹ̀, tí ó yà sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ọ, bí o bá pa òfin rẹ̀ mọ́, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.