Deu 28:65-67
Deu 28:65-67 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati lãrin orilẹ-ède wọnyi ni iwọ ki yio ri irọrun, bẹ̃li atẹlẹsẹ̀ rẹ ki yio ri isimi: ṣugbọn OLUWA yio fi iwarìri àiya, ati oju jijoro, ati ibinujẹ ọkàn fun ọ: Ẹmi rẹ yio sọrọ̀ ni iyemeji li oju rẹ; iwọ o si ma bẹ̀ru li oru ati li ọsán, iwọ ki yio si ní idaniloju ẹmi rẹ. Li owurọ̀ iwọ o wipe, Alẹ iba jẹ́ lẹ! ati li alẹ iwọ o wipe, Ilẹ iba jẹ́ mọ́! nitori ibẹ̀ru àiya rẹ ti iwọ o ma bẹ̀ru, ati nitori iran oju rẹ ti iwọ o ma ri.
Deu 28:65-67 Yoruba Bible (YCE)
Ara kò ní rọ̀ yín rárá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní rí ìdí jókòó. OLUWA yóo mú jìnnìjìnnì ati ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ba yín, yóo sì mú kí ojú yín di bàìbàì. Ninu hílàhílo ni ẹ óo máa wà nígbà gbogbo, ninu ẹ̀rù ati ìpayà ni ẹ óo máa wà tọ̀sán-tòru. Àwọn ohun tí ojú yín yóo máa rí yóo kó ìpayà ati ẹ̀rù ba yín, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ilẹ̀ bá ti ṣú, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti mọ́; bí ilẹ̀ bá sì ti tún mọ́, yóo dàbí kí ilẹ̀ ti ṣú.
Deu 28:65-67 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ kì yóò sinmi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà, kò sí ibi ìsinmi fún àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ. Níbẹ̀ ni OLúWA yóò ti fún ọ ní ọkàn ìnàngà, àárẹ̀ ojú, àti àìnírètí àyà. Ìwọ yóò gbé ní ìdádúró ṣinṣin, kún fún ìbẹ̀rùbojo lọ́sàn án àti lóru, bẹ́ẹ̀ kọ́ láé ni ìwọ yóò rí i ní àrídájú wíwà láyé rẹ. Ìwọ yóò wí ní òwúrọ̀ pé, “Bí ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ nìkan ni!” Nítorí ẹ̀rù tí yóò gba ọkàn rẹ àti ìran tí ojú rẹ yóò máa rí.