Deu 28:1-2
Deu 28:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
YIO si ṣe, bi iwọ ba farabalẹ gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe aṣẹ rẹ̀ gbogbo ti mo pa fun ọ li oni, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé ọ ga jù gbogbo orilẹ-ède aiye lọ: Gbogbo ibukún wọnyi yio si ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ, bi iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ.
Deu 28:1-2 Yoruba Bible (YCE)
“Bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o sì farabalẹ̀ pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo ṣe fún ọ lónìí mọ́, OLUWA Ọlọrun rẹ yóo gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù láyé lọ. Gbogbo ibukun wọnyi ni yóo mọ́ ọ lórí, tí yóo sì ṣẹ sí ọ lára, bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ.
Deu 28:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí OLúWA Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ. Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí OLúWA Ọlọ́run rẹ