Deu 28:1-11
Deu 28:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
YIO si ṣe, bi iwọ ba farabalẹ gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe aṣẹ rẹ̀ gbogbo ti mo pa fun ọ li oni, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé ọ ga jù gbogbo orilẹ-ède aiye lọ: Gbogbo ibukún wọnyi yio si ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ, bi iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ. Ibukún ni fun ọ ni ilu, ibukún ni fun ọ li oko. Ibukún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ati irú ohunọ̀sin rẹ, ati ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ. Ibukún ni fun agbọ̀n rẹ ati fun ọpọ́n-ipò-àkara rẹ. Ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba wọle, ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba jade. OLUWA yio mu awọn ọtá rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlù niwaju rẹ: nwọn o jade si ọ li ọ̀na kan, nwọn o si sá niwaju rẹ li ọ̀na meje. OLUWA yio paṣẹ ibukún sori rẹ ninu aká rẹ, ati ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé; on o si busi i fun ọ ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ. OLUWA yio fi idi rẹ kalẹ li enia mimọ́ fun ara rẹ̀, bi o ti bura fun ọ, bi iwọ ba pa aṣẹ ỌLUWA Ọlọrun rẹ mọ́, ti iwọ si rìn li ọ̀na rẹ̀. Gbogbo enia aiye yio si ri pe orukọ OLUWA li a fi npè ọ; nwọn o si ma bẹ̀ru rẹ. OLUWA yio si sọ ọ di pupọ̀ fun rere, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu irú ohunọ̀sin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, ni ilẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ lati fun ọ.
Deu 28:1-11 Yoruba Bible (YCE)
“Bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ, tí o sì farabalẹ̀ pa gbogbo òfin rẹ̀, tí mo ṣe fún ọ lónìí mọ́, OLUWA Ọlọrun rẹ yóo gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù láyé lọ. Gbogbo ibukun wọnyi ni yóo mọ́ ọ lórí, tí yóo sì ṣẹ sí ọ lára, bí o bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun rẹ. “OLUWA yóo bukun ọ ní ààrin ìlú, yóo sì bukun oko rẹ. “Yóo bukun àwọn ọmọ rẹ, ati èso ilẹ̀ rẹ, ati àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ, ati àwọn ọmọ mààlúù rẹ, ati àwọn ọmọ aguntan rẹ. “OLUWA yóo fi ibukun rẹ̀ sí orí ọkà rẹ, ati oúnjẹ rẹ. “Yóo bukun ọ nígbà tí o bá ń wọlé, yóo sì tún bukun ọ nígbà tí o bá ń jáde. “Yóo bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá tí ó bá dìde sí ọ. Bí wọ́n bá gba ọ̀nà kan dìde sí ọ, yẹ́lẹyẹ̀lẹ ni wọn óo fọ́nká nígbà tí wọn bá ń sálọ fún ọ. “OLUWA yóo bukun ìkórè inú àká rẹ, ati gbogbo nǹkan tí o bá dáwọ́ lé. OLUWA Ọlọrun rẹ yóo bukun ọ ní ilẹ̀ tí ó fún ọ. “OLUWA yóo ṣe ọ́ ní eniyan rẹ̀, tí ó yà sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún ọ, bí o bá pa òfin rẹ̀ mọ́, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Gbogbo eniyan ayé ni yóo rí i pé orúkọ OLUWA ni wọ́n fi ń pè ọ́, wọn yóo sì máa bẹ̀rù rẹ. OLUWA óo fún ọ ní ọpọlọpọ ọmọ, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn. Àwọn igi eléso rẹ yóo máa so jìnwìnnì ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun rẹ búra fún àwọn baba rẹ, pé òun yóo fún ọ.
Deu 28:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí OLúWA Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ. Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí OLúWA Ọlọ́run rẹ: Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko. Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ. Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ. Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde. OLúWA yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje. OLúWA yóò rán ìbùkún sí ọ àti sí ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ rẹ lé. OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò bùkún un fún ọ nínú ilẹ̀ tí ó ń fi fún ọ. OLúWA yóò fi ọ́ múlẹ̀ bí ènìyàn mímọ́, bí ó ti ṣe ìlérí fún ọ lórí ìbúra, bí o bá pa àṣẹ OLúWA Ọlọ́run rẹ mọ́ tí o sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé yóò rí i pé a pè ọ́ ní orúkọ OLúWA, wọn yóò sì bẹ̀rù rẹ. OLúWA yóò fi àlàáfíà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, fún ọmọ inú rẹ, irú ohun ọ̀sìn rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá rẹ láti fún ọ.