Deu 20:3-4
Deu 20:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki o si wi fun wọn pe, Gbọ́, Israeli, li oni ẹnyin sunmọ ogun si awọn ọtá nyin: ẹ máṣe jẹ ki àiya nyin ki o ṣojo, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe warìri, bẹ̃ni ẹ má si ṣe fòya nitori wọn; Nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ni mbá nyin lọ, lati bá awọn ọtá nyin jà fun nyin, lati gbà nyin là.
Deu 20:3-4 Yoruba Bible (YCE)
‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, tí ẹ̀ ń lọ sí ojú ogun lónìí láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àyà yín já, ẹ̀rù kò sì gbọdọ̀ bà yín, ẹ kò gbọdọ̀ wárìrì tabi kí ẹ jẹ́ kí jìnnìjìnnì dà bò yín. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ati láti fun yín ní ìṣẹ́gun.’
Deu 20:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Israẹli, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀tá rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi ààyè fún ìjayà níwájú u wọn. Nítorí OLúWA Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.”