Deu 20:1-9

Deu 20:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, ti iwọ si ri ẹṣin, ati kẹkẹ́-ogun, ati awọn enia ti o pọ̀ jù ọ, máṣe bẹ̀ru wọn: nitori OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá. Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba sunmọ ogun na, ki alufa ki o sunmọtosi, ki o si sọ̀rọ fun awọn enia. Ki o si wi fun wọn pe, Gbọ́, Israeli, li oni ẹnyin sunmọ ogun si awọn ọtá nyin: ẹ máṣe jẹ ki àiya nyin ki o ṣojo, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe warìri, bẹ̃ni ẹ má si ṣe fòya nitori wọn; Nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ni mbá nyin lọ, lati bá awọn ọtá nyin jà fun nyin, lati gbà nyin là. Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia, pe, Ọkunrin wo li o kọ ile titun, ti kò ti ikó si i? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba kó si i. Ati ọkunrin wo li o gbìn ọgbà-àjara, ti kò si ti ijẹ ninu rẹ̀? jẹ ki on pẹlu ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba jẹ ẹ. Ati ọkunrin wo li o fẹ́ iyawo, ti kò ti igbé e? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba gbé e. Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia na si i, ki nwọn ki o si wipe, Ọkunrin wo li o wà ti o bẹ̀ru ti o si nṣojo? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki àiya awọn arakunrin rẹ̀ ki o má ba ṣojo pẹlu bi àiya tirẹ̀. Yio si ṣe, nigbati awọn olori-ogun ba pari ọ̀rọ sisọ fun awọn enia tán, ki nwọn ki o si fi awọn balogun jẹ lori awọn enia na.

Deu 20:1-9 Yoruba Bible (YCE)

“Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, tí ẹ bá rí ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wà pẹlu yín. Nígbà tí ẹ bá súnmọ́ ojú ogun, kí alufaa jáde kí ó sì bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, kí ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, tí ẹ̀ ń lọ sí ojú ogun lónìí láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àyà yín já, ẹ̀rù kò sì gbọdọ̀ bà yín, ẹ kò gbọdọ̀ wárìrì tabi kí ẹ jẹ́ kí jìnnìjìnnì dà bò yín. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ati láti fun yín ní ìṣẹ́gun.’ “Lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀gágun yóo wí fún àwọn eniyan náà pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ilé titun, tí kò tíì yà á sí mímọ́? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ ya ilé rẹ̀ sí mímọ́, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo ya ilé rẹ̀ sí mímọ́. Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbin ọgbà àjàrà, tí kò sì tíì jẹ ninu èso rẹ̀? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo jẹ èso ọgbà àjàrà rẹ̀. Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ iyawo sọ́nà tí kò tíì gbé e wọlé? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má baà jẹ́ pé bí ó bá kú sí ogun, ẹlòmíràn ni yóo fẹ́ iyawo rẹ̀.’ “Àwọn ọ̀gágun yóo tún bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ọkunrin kan wà ninu yín tí ẹ̀rù ń bà, tabi tí àyà rẹ̀ ń já? Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ pada sí ilé, kí ó má baà kó ojora bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.’ Nígbà tí àwọn ọ̀gágun bá parí ọ̀rọ̀ tí wọn ń bá àwọn eniyan náà sọ, wọn óo yan àwọn kan tí wọn óo máa ṣe aṣaaju ìsọ̀rí-ìsọ̀rí àwọn jagunjagun.

Deu 20:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀tá rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí OLúWA Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, yóò wà pẹ̀lú rẹ. Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá síwájú, yóò sì bá ọmọ-ogun sọ̀rọ̀, yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Israẹli, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀tá rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi ààyè fún ìjayà níwájú u wọn. Nítorí OLúWA Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.” Àwọn olórí ogun yóò sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó kọ́ ilé tuntun tí kò sì tì ì yà á sọ́tọ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí ó lè kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbà á. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó gbin ọgbà àjàrà kan tí kò sì tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ń gbádùn rẹ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbádùn rẹ̀. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wá ògo obìnrin kan tí kò ì tí ì fẹ́ ẹ? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì fẹ́ ẹ.” Nígbà náà ni olórí yóò tún fi kún un pé “Ǹjẹ́ ọkùnrin kankan ń bẹ̀rù tàbí páyà? Jẹ́ kí ó lọ ilé nítorí kí arákùnrin rẹ̀ má ba à wá tún dáyà fò ó.” Nígbà tí olórí ogun bá ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn, wọn yóò yan olórí ogun lórí i rẹ̀.