Deu 20:1-4
Deu 20:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀tá rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí OLúWA Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, yóò wà pẹ̀lú rẹ. Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá síwájú, yóò sì bá ọmọ-ogun sọ̀rọ̀, yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Israẹli, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀tá rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi ààyè fún ìjayà níwájú u wọn. Nítorí OLúWA Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.”
Deu 20:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, ti iwọ si ri ẹṣin, ati kẹkẹ́-ogun, ati awọn enia ti o pọ̀ jù ọ, máṣe bẹ̀ru wọn: nitori OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá. Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba sunmọ ogun na, ki alufa ki o sunmọtosi, ki o si sọ̀rọ fun awọn enia. Ki o si wi fun wọn pe, Gbọ́, Israeli, li oni ẹnyin sunmọ ogun si awọn ọtá nyin: ẹ máṣe jẹ ki àiya nyin ki o ṣojo, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe warìri, bẹ̃ni ẹ má si ṣe fòya nitori wọn; Nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ni mbá nyin lọ, lati bá awọn ọtá nyin jà fun nyin, lati gbà nyin là.
Deu 20:1-4 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí ẹ bá jáde lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, tí ẹ bá rí ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n pọ̀ jù yín lọ, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn, nítorí OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wà pẹlu yín. Nígbà tí ẹ bá súnmọ́ ojú ogun, kí alufaa jáde kí ó sì bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, kí ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, tí ẹ̀ ń lọ sí ojú ogun lónìí láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àyà yín já, ẹ̀rù kò sì gbọdọ̀ bà yín, ẹ kò gbọdọ̀ wárìrì tabi kí ẹ jẹ́ kí jìnnìjìnnì dà bò yín. Nítorí OLUWA Ọlọrun yín ń ba yín lọ láti bá àwọn ọ̀tá yín jà, ati láti fun yín ní ìṣẹ́gun.’