Deu 18:15-19
Deu 18:15-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé wolĩ kan dide fun ọ lãrin rẹ, ninu awọn arakunrin rẹ, bi emi; on ni ki ẹnyin ki o fetisi; Gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ bère lọwọ OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu li ọjọ́ ajọ nì, wipe, Máṣe jẹ ki emi tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun mi mọ́, bẹ̃ni ki emi ki o má tun ri iná nla yi mọ́; ki emi ki o mà ba kú. OLUWA si wi fun mi pe, Nwọn wi rere li eyiti nwọn sọ. Emi o gbé wolĩ kan dide fun wọn lãrin awọn arakunrin wọn, bi iwọ; emi o si fi ọ̀rọ mi si i li ẹnu, on o si sọ fun wọn gbogbo eyiti mo palaṣẹ. Yio si ṣe, ẹniti kò ba fetisi ọ̀rọ mi ti on o ma sọ li orukọ mi, emi o bère lọwọ rẹ̀.
Deu 18:15-19 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan dìde tí yóo dàbí mi láàrin yín, tí yóo jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín, òun ni kí ẹ máa gbọ́ràn sí lẹ́nu. “Bíi ti ọjọ́ tí ẹ péjọ ní òkè Horebu tí ẹ bẹ OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sọ fún mi pé, ‘Má jẹ́ kí á gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa mọ́, tabi kí á rí iná ńlá yìí mọ́; kí á má baà kú.’ OLUWA wí fún mi nígbà náà pé, ‘Gbogbo ohun tí wọ́n sọ patapata ni ó dára. N óo gbé wolii kan dìde gẹ́gẹ́ bíì rẹ, láàrin àwọn arakunrin wọn, n óo fi ọ̀rọ̀ mi sí i lẹ́nu, yóo sì máa sọ ohun gbogbo tí mo bá pa láṣẹ fún wọn. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí yóo máa sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra mi ni n óo jẹ olúwarẹ̀ níyà.
Deu 18:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrín àwọn arákùnrin rẹ. Tìrẹ ni kí o gbọ́. Nítorí èyí ni ohun tí ìwọ béèrè lọ́wọ́ OLúWA Ọlọ́run rẹ ní Horebu ní ọjọ́ àjọ, nígbà tí ìwọ wí pé, “Kí àwa má ṣe gbọ́ ohùn OLúWA Ọlọ́run wa tàbí rí iná ńlá yìí mọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò kú.” OLúWA sì wí fún mi pé, “Ohun tí wọ́n sọ dára. Èmi yóò gbé wòlíì kan dìde fún wọn láàrín àwọn arákùnrin wọn bí ìwọ, Èmi yóò fi ọ̀rọ̀ mi sí i ní ẹnu, yóò sì sọ fún wọn gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un. Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi tí wòlíì náà yóò sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra à mi yóò sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.