Deu 18:10-11
Deu 18:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki a máṣe ri ninu nyin ẹnikan ti nmu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là iná já, tabi ti nfọ̀ afọ̀ṣẹ, tabi alakiyesi-ìgba, tabi aṣefàiya, tabi ajẹ́, Tabi atuju, tabi aba-iwin-gbìmọ, tabi oṣó, tabi abokulò.
Pín
Kà Deu 18Deu 18:10-11 Yoruba Bible (YCE)
Ẹnikẹ́ni ninu yín kò gbọdọ̀ fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, kì báà ṣe ọmọ rẹ̀ obinrin tabi ọkunrin. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ máa wo iṣẹ́ kiri tabi kí ó di aláfọ̀ṣẹ tabi oṣó; tabi kí ó máa sa òògùn sí ẹlòmíràn, tabi kí ó máa bá àwọn àǹjọ̀nú sọ̀rọ̀, tabi kí ó di abókùúsọ̀rọ̀.
Pín
Kà Deu 18Deu 18:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Má ṣe jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrín yín tí ó fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin la iná já (fi ọmọ rẹ rú ẹbọ) kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ fọ àfọ̀ṣẹ, tàbí ṣẹ́ oṣó, tàbí túmọ̀ àwọn ààmì nǹkan tí ń bọ̀, tàbí àjẹ́, tàbí afògèdè, tàbí jẹ́ a bá iwin gbìmọ̀ tàbí oṣó tàbí abókùúsọ̀rọ̀.
Pín
Kà Deu 18