Deu 15:7-8
Deu 15:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi talakà kan ba mbẹ ninu nyin, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ, ninu ibode rẹ kan, ni ilẹ rẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o máṣe mu àiya rẹ le si i, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe há ọwọ́ rẹ si talakà arakunrin rẹ: Sugbọn lilà ni ki iwọ ki o là ọwọ́ rẹ fun u, ki iwọ ki o si wín i li ọ̀pọlọpọ tó fun ainí rẹ̀, li ohun ti nfẹ́.
Deu 15:7-8 Yoruba Bible (YCE)
“Bí ẹnìkan ninu yín, tí ó jẹ́ arakunrin yín, bá jẹ́ talaka, tí ó sì wà ninu ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó wà ninu ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ dijú sí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ háwọ́ sí arakunrin yín tí ó jẹ́ talaka yìí. Ẹ gbọdọ̀ lawọ́ sí i, kí ẹ sì yá a ní ohun tí ó tó láti tán gbogbo àìní rẹ̀, ohunkohun tí ó wù kí ó lè jẹ́.
Deu 15:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí tálákà kan bá wà láàrín àwọn arákùnrin yín ní èyíkéyìí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí OLúWA yín yóò fún un yín. Ẹ má ṣe ṣe àìláàánú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà. Ṣùgbọ́n ẹ lawọ́ kí ẹ sì fi tọkàntọkàn yá wọn ní ohun tí wọ́n nílò.