Deu 11:26-28
Deu 11:26-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wò o, emi fi ibukún ati egún siwaju nyin li oni; Ibukún, bi ẹnyin ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni: Ati egún, bi ẹnyin kò ba gbà ofin OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́ ti ẹnyin ba si yipada kuro li ọ̀na ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, lati ma tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ti ẹnyin kò mọ̀ rí.
Deu 11:26-28 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ wò ó, mo gbé ibukun ati ègún kalẹ̀ níwájú yín lónìí. Ibukun ni fun yín bí ẹ bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí mo fun yín lónìí yìí. Ṣugbọn ègún ni fun yín bí ẹ kò bá tẹ̀lé òfin OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ bá yà kúrò lójú ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fun yín lónìí, tí ẹ bá ń sin àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ rí.
Deu 11:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ kíyèsi i, mo fi ìbùkún àti ègún lélẹ̀ níwájú u yín lónìí: ìbùkún ni, bí ẹ bá pa òfin OLúWA Ọlọ́run yín, tí mo ń fún un yín lónìí mọ́. Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin OLúWA Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tí ì mọ̀.