Deu 11:24-25
Deu 11:24-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibi gbogbo ti atẹlẹsẹ̀ nyin ba tẹ̀ yio jẹ́ ti nyin: lati aginjù nì, ati Lebanoni, lati odò nla nì, odò Euferate, ani dé ikẹhin okun ni yio jẹ́ opinlẹ nyin. Kò sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju nyin: OLUWA Ọlọrun nyin, yio fi ìbẹru nyin ati ìfoiya nyin sara gbogbo ilẹ ti ẹnyin o tẹ̀, bi on ti wi fun nyin.
Deu 11:24-25 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ yín bá tẹ̀, ẹ̀yin ni ẹ óo ni ín. Ilẹ̀ yín yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Lẹbanoni, ati láti odò Yufurate títí dé Òkun tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. Kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo lè dojú kọ yín, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú kí ẹ̀rù yín máa ba gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ tí ẹ óo máa rìn kọjá, jìnnìjìnnì yín yóo sì máa bò wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti ṣe ìlérí fun yín.

Deu 11:24-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀ ni yóò jẹ́ tiyín, ilẹ̀ ẹ yín yóò gbilẹ̀ láti aginjù dé Lebanoni, àti láti odò Eufurate dé Òkun ìwọ̀-oòrùn. Kò sí ẹni náà tí yóò lè kò yín lójú ìjà, OLúWA Ọlọ́run yín yóò fi ẹ̀rù àti ìwárìrì i yín sórí gbogbo ilẹ̀ náà bí ó ti ṣèlérí fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá lọ.