Deu 11:13-14
Deu 11:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Yio si ṣe, bi ẹnyin ba fetisi ofin mi daradara, ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo, ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo, Nigbana li emi o ma fun nyin li òjo ilẹ nyin li akokò rẹ̀, òjo akọ́rọ̀ ati òjo àrọkuro, ki iwọ ki o le ma kó ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ sinu ile.
Deu 11:13-14 Yoruba Bible (YCE)
“Tí ẹ bá tẹ̀lé òfin mi tí mo fun yín lónìí, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì sìn ín pẹlu gbogbo ọkàn ati ẹ̀mí yín, yóo rọ òjò sórí ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀, ati òjò àkọ́rọ̀ ati ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ baà lè kórè ọkà, ọtí waini, ati òróró olifi yín.
Deu 11:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ tí mo fún un yín lónìí tọkàntọkàn: tí ẹ fẹ́ràn OLúWA Ọlọ́run yín, tí ẹ sì sìn ín, pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn yín: nígbà náà, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ ẹ yín lákòókò rẹ̀, àti òjò àkọ́rọ̀ àti ti àrọ̀kẹ́yìn, kí ẹ ba à lè kórè oúnjẹ yín wọlé àní wáìnì tuntun àti òróró.