Dan 9:20-27

Dan 9:20-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bi emi si ti nwi, ti emi ngbadura, ati bi emi si ti njẹwọ ẹṣẹ mi, ati ẹ̀ṣẹ Israeli awọn enia mi, ti emi si ngbé ẹbẹ mi kalẹ niwaju Oluwa, Ọlọrun mi, nitori òke mimọ́ Ọlọrun mi. Bẹni, bi mo ti nwi lọwọ ninu adura mi, ọkunrin na, Gabrieli ti mo ti ri ni iran mi li atetekọṣe, li a mu lati fò wá kankan, o de ọdọ mi niwọn akokò ẹbọ aṣãlẹ. O mu mi mọ̀, o si mba mi sọ̀rọ wipe, Danieli, mo jade wá nisisiyi lati fi oye fun ọ. Ni ipilẹṣẹ ẹ̀bẹ rẹ li ọ̀rọ ti jade wá, emi si wá lati fi hàn fun ọ, nitoriti iwọ iṣe ayanfẹ gidigidi: nitorina, moye ọ̀ran na, ki o si kiyesi iran na. Adọrin ọ̀sẹ li a pinnu sori awọn enia rẹ, ati sori ilu mimọ́ rẹ, lati ṣe ipari irekọja, ati lati fi edidi di ẹ̀ṣẹ, ati lati ṣe ilaja fun aiṣedẽde ati lati mu ododo ainipẹkun wá ati lati ṣe edidi iran ati woli, ati lati fi ororo yàn Ẹni-mimọ́ julọ nì. Nitorina ki iwọ ki o mọ̀, ki o si ye ọ, pe lati ijade lọ ọ̀rọ na lati tun Jerusalemu ṣe, ati lati tun u kọ́, titi de igba ọmọ-alade Ẹni-ororo na, yio jẹ ọ̀sẹ meje, ati ọ̀sẹ mejilelọgọta: a o si tun igboro rẹ̀ ṣe, a o mọdi rẹ̀, ṣugbọn ni igba wahala. Lẹhin ọ̀sẹ mejilelọgọta na li a o ke Ẹni-ororo na kuro, kì yio si si ẹnikan fun u, ati awọn enia ọmọ-alade kan ti yio wá ni yio pa ilu na ati ibi-mimọ́ run; opin ẹniti mbọ yio dabi ikún omi, ati ogun titi de opin, eyi ni ipari idahoro. On o si fi idi majẹmu kan mulẹ fun ọ̀pọlọpọ niwọn ọ̀sẹ kan: ati lãrin ọ̀sẹ na ni yio mu ki a dẹkun ẹbọ, ati ọrẹ-ẹbọ, irira isọdahoro yio si duro lori ibi-mimọ́ titi idajọ ti a pinnu yio túdà sori asọnidahoro.

Dan 9:20-27 Yoruba Bible (YCE)

Mo bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, mò ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ èmi ati ti àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, mo kó ẹ̀bẹ̀ mi tọ OLUWA Ọlọrun mi lọ, nítorí òkè mímọ́ rẹ̀. Bí mo ti ń gbadura, ni Geburẹli, tí mo rí lójúran ní àkọ́kọ́ bá yára fò wá sọ́dọ̀ mi, ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́. Ó wá ṣe àlàyé fún mi, ó ní, “Daniẹli, àlàyé ìran tí o rí ni mo wá ṣe fún ọ. Bí o ti bẹ̀rẹ̀ sí gbadura ni àṣẹ dé, òun ni mo sì wá sọ fún ọ́; nítorí àyànfẹ́ ni ọ́. Nisinsinyii, farabalẹ̀ ṣàkíyèsí ọ̀rọ̀ náà, kí òye ìran náà sì yé ọ. “Ọlọrun ti fi àṣẹ sí i pé, lẹ́yìn aadọrin ọdún lọ́nà meje ni òun óo tó dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ ati ti ìlú mímọ́ rẹ jì wọ́n, tí òun óo ṣe ètùtù fún ìwà burúkú wọn, tí òun óo mú òdodo ainipẹkun ṣẹ, tí òun óo fi èdìdì di ìran ati àsọtẹ́lẹ̀ náà, tí òun óo sì fi òróró ya Ilé Mímọ́ Jùlọ rẹ̀ sọ́tọ̀. Mọ èyí, kí ó sì yé ọ, pé láti ìgbà tí àṣẹ bá ti jáde lọ láti tún Jerusalẹmu kọ́, di ìgbà tí ẹni àmì òróró Ọlọrun, tíí ṣe ọmọ Aládé, yóo dé, yóo jẹ́ ọdún meje lọ́nà meje. Lẹ́yìn náà, ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje ni a óo sì fi tún un kọ́, yóo ní òpópónà, omi yóo sì yí i po; ṣugbọn yóo jẹ́ àkókò ìyọnu. Lẹ́yìn ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje yìí, wọn óo pa ẹni àmì òróró Ọlọrun kan láìṣẹ̀. Àwọn ọmọ ogun alágbára kan tí yóo joyè, yóo pa Jerusalẹmu ati Tẹmpili run. Òpin óo dé bá a bí àgbàrá òjò, ogun ati ìsọdahoro tí a ti fi àṣẹ sí yóo dé. Ìjòyè yìí yóo bá ọpọlọpọ dá majẹmu ọdún meje tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Fún ìdajì ọdún meje náà, yóo fi òpin sí ẹbọ rírú ati ọrẹ. Olùsọdahoro yóo gbé ohun ìríra ka téńté orí pẹpẹ ní Jerusalẹmu. Ohun ìríra náà yóo sì wà níbẹ̀ títí tí ìgbẹ̀yìn tí Ọlọrun ti fàṣẹ sí yóo fi dé bá olùsọdahoro náà.”

Dan 9:20-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, tí mo sì ń gba àdúrà, tí mo ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Israẹli ènìyàn mi, tí mo sì ń mú ẹ̀bẹ̀ mi tọ OLúWA Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ rẹ. Bí mo ṣe ń gba àdúrà náà lọ́wọ́, Gebrieli ọkùnrin tí mo rí nínú ìran ìṣáájú, yára kánkán wá sí ọ̀dọ̀ mi ní àkókò ẹbọ àṣálẹ́. Ó jẹ́ kí ó yé mi, ó sì wí fún mi pé, “Daniẹli, mo wá láti jẹ́ kí o mọ̀ kí o sì ní òye. Bí o ṣe bẹ̀rẹ̀ sí nígbà àdúrà, a fún ọ ní ìdáhùn kan, èyí tí mo wá láti sọ fún ọ, nítorí ìwọ jẹ́ àyànfẹ́ gidigidi. Nítorí náà, gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò kí ìran náà sì yé ọ: “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ni a pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ àti fún àwọn ìlú mímọ́ rẹ láti parí ìrékọjá, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, láti ṣe ètùtù sí ìwà búburú, láti mú òdodo títí ayé wá, láti ṣe èdìdì ìran àti wòlíì àti láti fi òróró yan ẹni mímọ́ jùlọ. “Nítorí náà, mọ èyí pé: Láti ìgbà tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà jáde wí pé kí a tún Jerusalẹmu ṣe, kí a sì tún kọ́, títí dé ìgbà ọmọ-aládé Ẹni òróró náà, alákòóso wa yóò fi dé, ó jẹ́ ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó sì tún ìgboro àti yàrá rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà ni. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó ké Ẹni òróró náà kúrò, kò sì ní ní ohun kan. Àwọn ènìyàn ọmọ-aládé náà tí yóò wá ni yóò pa ìlú náà àti ibi mímọ́ run. Òpin yóò dé bí ìkún omi: ogun yóò máa jà títí dé òpin, a sì ti pàṣẹ ìdahoro. Yóò sì fi ìdí i májẹ̀mú kan múlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ní àárín ọ̀sẹ̀ ni yóò mú òpin bá ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ. Àti lórí apá kan ni yóò dà ìríra tí ó mú ìdahoro wá, títí tí òpin tí a ti pàṣẹ lórí asọnidahoro yóò fi padà fi dé bá a.”