Dan 9:1-19

Dan 9:1-19 Bibeli Mimọ (YBCV)

LI ọdun kini Dariusi, ọmọ Ahasuerusi, lati iru-ọmọ awọn ara Media wá, ti a fi jọba lori ilẹ-ọba awọn ara Kaldea; Li ọdun kini ijọba rẹ̀ li emi Danieli fiyesi lati inu iwe, iye ọdun, nipa eyi ti ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah, woli wá, pe adọrin ọdun li on o mu pé lori idahoro Jerusalemu. Emi si kọju mi si Oluwa Ọlọrun, lati ma ṣafẹri nipa adura ati ẹ̀bẹ, pẹlu àwẹ, ninu aṣọ-ọ̀fọ, ati ẽru. Emi si gbadura si Oluwa Ọlọrun mi, mo si ṣe ijẹwọ mi, mo si wipe, Oluwa, iwọ Ọlọrun ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ti npa majẹmu ati ãnu mọ́ fun awọn ti o fẹ ẹ, ati fun awọn ti o pa ofin rẹ̀ mọ́; Awa ti ṣẹ̀, awa si ti nda ẹ̀ṣẹ, awa si ti ṣe buburu gidigidi, awa si ti ṣọ̀tẹ, ani nipa kikuro ninu ẹkọ́ rẹ, ati idajọ rẹ: Bẹ̃li awa kò si fi eti si awọn iranṣẹ rẹ, awọn woli, ti o sọ̀rọ li orukọ rẹ fun awọn ọba wa, awọn ọmọ-alade wa, ati awọn baba wa, ati fun gbogbo awọn enia ilẹ wa. Oluwa tirẹ li ododo, ṣugbọn tiwa ni itiju, gẹgẹ bi o ti ri loni; fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu, ati fun gbogbo Israeli, ti o sunmọ tosi, ati awọn ti o jina rére; ni gbogbo ilẹkilẹ, nibiti o gbe ti le wọn rè, nitori ẹ̀ṣẹ wọn ti nwọn ti ṣẹ̀ si ọ. Oluwa, tiwa ni itiju, ti awọn ọba wa, ati awọn olori wa, ati ti awọn baba wa, nitori ti awa ti ṣọ̀tẹ si ọ. Sibẹ ti Oluwa Ọlọrun wa li ãnu ati idariji bi awa tilẹ ṣọ̀tẹ si i; Bẹ̃li awa kò si gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, lati ma rìn nipa ofin ti o gbé kalẹ niwaju wa lati ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli wá. Bẹ̃ni gbogbo Israeli ti ṣẹ̀ si ofin rẹ, ani nipa kikuro, ki nwọn ki o máṣe gbà ohùn rẹ gbọ́; nitorina li a ṣe yi egún dà si ori wa, ati ibura na ti a kọ sinu ofin Mose, iranṣẹ Ọlọrun, nitori ti awa ti ṣẹ̀ si i. On si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, eyi ti o sọ si wa, ati si awọn onidajọ wa ti o nṣe idajọ fun wa, nipa eyi ti o fi mu ibi nla bá wa: iru eyi ti a kò ti iṣe si gbogbo abẹ ọrun, gẹgẹ bi a ti ṣe sori Jerusalemu. Gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, gbogbo ibi wọnyi wá sori wa: bẹ̃li awa kò si wá ojurere niwaju Oluwa, Ọlọrun wa, ki awa ki o le yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa, ki a si moye otitọ rẹ. Nitorina li Oluwa ṣe fiyesi ibi na, ti o si mu u wá sori wa; nitoripe olododo li Oluwa Ọlọrun wa ni gbogbo iṣẹ rẹ̀ ti o nṣe: ṣugbọn awa kò gbà ohùn rẹ̀ gbọ́. Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun wa, iwọ ti o ti fi ọwọ agbara mu awọn enia rẹ jade lati Egipti wá, ti iwọ si ti gba orukọ fun ara rẹ gẹgẹ bi o ti wà loni: awa ti ṣẹ̀, awa si ti ṣe buburu gidigidi. Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo ododo rẹ, lõtọ, jẹ ki ibinu ati irunu rẹ yi kuro lori Jerusalemu, ilu rẹ, òke mimọ́ rẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wa, ati ẹ̀ṣẹ awọn baba wa ni Jerusalemu, ati awọn enia rẹ fi di ẹ̀gan si gbogbo awọn ti o yi wa ka. Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, gbọ́ adura ọmọ-ọdọ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, ki o si mu ki oju rẹ ki o mọlẹ si ibi-mimọ́ rẹ ti o dahoro, nitori ti Oluwa. Tẹ eti rẹ silẹ, Ọlọrun mi, ki o si gbọ́: ṣi oju rẹ, ki o si wò idahoro wa, ati ilu ti a nfi orukọ rẹ pè: nitoriti awa kò gbé ẹ̀bẹ wa kalẹ niwaju rẹ nitori ododo wa, ṣugbọn nitori ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ nla. Oluwa, gbọ́, Oluwa, dariji: Oluwa, tẹ eti rẹ silẹ ki o si ṣe; máṣe jafara, nitori ti iwọ tikararẹ, Ọlọrun mi: nitori orukọ rẹ li a fi npè ilu rẹ, ati awọn enia rẹ.

Dan 9:1-19 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọdún kinni tí Dariusi, ọmọ Ahasu-erusi, ará Mede, jọba ní Babiloni, èmi, Daniẹli bẹ̀rẹ̀ sí ka ọ̀rọ̀ OLUWA, mò ń ronú lórí ohun tí Jeremaya, wolii sọ, pé Jerusalẹmu yóo dahoro fún aadọrin ọdún. Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ OLUWA Ọlọrun tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ mò ń gbadura tọkàntọkàn pẹlu ààwẹ̀; mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, mo sì jókòó sinu eérú. Mo gbadura sí OLUWA Ọlọrun mi, mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi. Mo ní, “OLUWA Ọlọrun, tí ó tóbi, tí ó bani lẹ́rù, tíí máa ń pa majẹmu ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹlu gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́. “A ti ṣẹ̀, a ti ṣe burúkú; a ti ṣìṣe, a ti ṣọ̀tẹ̀, nítorí pé a ti kọ òfin ati àṣẹ rẹ sílẹ̀. A kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn iranṣẹ rẹ, àní àwọn wolii, tí wọ́n wá jíṣẹ́ rẹ fún àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa, àwọn baba wa, ati fún gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà. Olódodo ni ọ́, OLUWA, ṣugbọn lónìí yìí ojú ti gbogbo àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu, ati gbogbo Israẹli; ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn, níbi gbogbo tí o fọ́n wọn káàkiri sí nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí ọ. OLUWA, ìtìjú yìí pọ̀ fún àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, ati àwọn baba wa, nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́. Aláàánú ni ọ́ OLUWA Ọlọrun wa, ò sì máa dáríjì ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. A kò gbọ́ tìrẹ OLUWA Ọlọrun wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò pa òfin rẹ tí o fi rán àwọn wolii, iranṣẹ rẹ sí wa mọ́. Gbogbo Israẹli ti rú òfin rẹ, wọ́n ti pada lẹ́yìn rẹ, wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́ tìrẹ. Nítorí náà, ègún ati ìbúra tí Mose, iranṣẹ rẹ kọ sinu ìwé òfin ti ṣẹ mọ́ wa lára. Ohun tí o sọ pé o óo ṣe sí àwa ati àwọn ọba wa náà ni o ṣe sí wa, tí àjálù ńlá fi dé bá wa. Irú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí kò ṣẹlẹ̀ sí ìlú kan rí, ninu gbogbo àwọn ìlú ayé yìí. Gbogbo ìyọnu tí a kọ sinu òfin Mose ti dé bá wa, sibẹ a kò wá ojurere OLUWA Ọlọrun wa, kí á yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí á sì tẹ̀lé ọ̀nà òtítọ́ rẹ̀. Nítorí náà, OLUWA ti mú kí ìyọnu dé bá wa, ó sì rọ̀jò rẹ̀ lé wa lórí; olódodo ni OLUWA Ọlọrun wa ninu gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, sibẹ a kò tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀. “Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun wa, ìwọ tí o kó àwọn eniyan rẹ jáde ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu agbára ńlá, nítorí orúkọ rẹ tí à ń ranti títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe nǹkan burúkú. OLUWA, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òdodo rẹ, dáwọ́ ibinu ati ìrúnú rẹ dúró lórí Jerusalẹmu, ìlú rẹ, òkè mímọ́ rẹ; nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára àwọn baba wa, ti sọ Jerusalẹmu ati àwọn eniyan rẹ, di àmúpòwe láàrin àwọn tí ó yí wa ká. Nítorí náà Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ. Nítorí orúkọ rẹ, OLUWA, ṣí ojurere wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti di ahoro. Gbọ́ tiwa, Ọlọrun mi, ṣíjú wò wá, bí àwa ati ìlú tí à ń pe orúkọ rẹ mọ́, ti wà ninu ìsọdahoro. Kì í ṣe nítorí òdodo wa ni a ṣe ń gbadura sí ọ, ṣugbọn nítorí pé aláàánú ni ọ́. Gbọ́ tiwa, OLUWA, dáríjì wá, tẹ́tí sí wa, OLUWA, wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí, má sì jẹ́ kí ó pẹ́, nítorí orúkọ rẹ, tí a fi ń pe ìlú rẹ ati àwọn eniyan rẹ.”

Dan 9:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọdún kìn-ín-ní Dariusi ọmọ Ahaswerusi, ẹni tí a bí ní Media, òun ló jẹ ọba lórí ìjọba Babeli. Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, èmi Daniẹli fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA tí wòlíì Jeremiah, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jerusalẹmu yóò fi wà ní ahoro. Nígbà náà, ni mo yípadà sí Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú àwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú. Mo gbàdúrà sí OLúWA Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́ wí pé: “Ìwọ OLúWA, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ó ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́. Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀. Àwa kò fetí sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ sí àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé àti àwọn baba wa, àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà. “Olúwa ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu àti gbogbo Israẹli ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìṣòótọ́ ọ wa sí ọ. Háà! OLúWA, àwa àti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn baba wa, ìtìjú dé bá wa nítorí àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ. Olúwa Ọlọ́run wa ní àánú, ó sì ń dáríjì, bí àwa tilẹ̀ ti ṣe ọ̀tẹ̀ sí i; Àwa kò gbọ́rọ̀ sí OLúWA Ọlọ́run wa, a kò sì pa àwọn òfin rẹ mọ́, èyí tí ó fún wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀. Gbogbo Israẹli ti ṣẹ̀ sí òfin rẹ, wọ́n ti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ. “Nígbà náà ni ègún àti ìdájọ́ tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìbúra nínú òfin Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run dà sórí i wa, nítorí tí àwa ti sẹ̀ sí ọ. Ìwọ ti mú ọ̀rọ̀ tí o sọ sí wa sẹ àti lórí àwọn alákòóso wa, nípa mímú kí ibi ńlá bá wa, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ọ̀run, bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu yìí. Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Mose bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ibi yìí ti dé bá wa, síbẹ̀ a kò bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere OLúWA Ọlọ́run wa, nípa yíyí padà kí a kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì mọ òtítọ́ rẹ. OLúWA kò jáfara láti mú ibi náà wá sórí wa, nítorí Olódodo ni OLúWA Ọlọ́run wa nínú u gbogbo ohun tí ó ń ṣe; síbẹ̀ àwa kò ṣe ìgbọ́ràn sí i. “Ní ìsinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run wa, ẹni tí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, pẹ̀lú ọwọ́ agbára, tí ó fún ara rẹ̀ ní orúkọ tí ó wà títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. OLúWA, ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jerusalẹmu ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa ti mú Jerusalẹmu àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká. “Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, nítorí i tìrẹ OLúWA, fi ojú àánú wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti dahoro. Tẹ́ etí rẹ sílẹ̀, Ọlọ́run, kí o gbọ́; ya ojú rẹ sílẹ̀, kí o sì wo ìdahoro ìlú tí a ń fi orúkọ rẹ pè. Àwa kò gbé ẹ̀bẹ̀ wa kalẹ̀ níwájú u rẹ nítorí pé a jẹ́ olódodo, bí kò ṣe nítorí àánú ńlá rẹ. OLúWA, fetísílẹ̀! OLúWA, Dáríjì! OLúWA, gbọ́ kí o sì ṣe é! Nítorí i tìrẹ, Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ títí, nítorí ìlú rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọ lára.”