Dan 8:5-8
Dan 8:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi mo si ti nwoye, kiyesi i, obukọ kan ti iha iwọ-õrùn jade wá sori gbogbo aiye, kò si fi ẹsẹ kan ilẹ: obukọ na si ni iwo nla kan lãrin oju rẹ̀. O si tọ̀ àgbo ti o ni iwo meji na wá, eyi ti mo ti ri ti o duro lẹba odò na, o si fi irunu agbara sare si i. Mo si ri i, o sunmọ ọdọ́-àgbo na, o si fi ikoro ibinu sare si i, o lu àgbo na bolẹ, o si ṣẹ́ iwo rẹ̀ mejeji: kò si si agbara ninu àgbo na, lati duro niwaju rẹ̀, ṣugbọn o lù u bolẹ o si tẹ̀ ẹ mọlẹ: kò si si ẹniti o le gbà àgbo na lọwọ rẹ̀. Nigbana ni obukọ na nṣe ohun nla pupọpupọ, nigbati o si di alagbara tan, iwo nla na ṣẹ́; ati nipò rẹ̀ iwo mẹrin miran ti iṣe afiyesi si yọ jade si ọ̀na afẹfẹ mẹrẹrin ọrun.
Dan 8:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Bí mo tí ń ronú nípa rẹ̀, mo rí i tí òbúkọ kan ti ìhà ìwọ̀ oòrùn la gbogbo ayé kọjá wá láìfi ẹsẹ̀ kan ilẹ̀, ó sì ní ìwo ńlá kan láàrin ojú rẹ̀ mejeeji. Ó súnmọ́ àgbò tí ó ní ìwo meji, tí mo kọ́ rí tí ó dúró létí odò, ó sì pa kuuru sí i pẹlu ibinu ńlá. Mo rí i ó súnmọ́ àgbò náà, ó fi tìbínú-tìbínú kàn án, ìwo mejeeji àgbò náà sì ṣẹ́. Àgbò náà kò lágbára láti dúró níwájú rẹ̀. Ó tì í ṣubú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. Kò sì sí ẹni tí ó lè gba àgbò náà lọ́wọ́ rẹ̀. Òbúkọ náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi sí i, ṣugbọn nígbà tí agbára rẹ̀ dé góńgó, ìwo ńlá iwájú rẹ̀ bá kán. Ìwo ńlá mẹrin mìíràn sì hù dípò rẹ̀. Wọ́n kọjú sí ọ̀nà mẹrẹẹrin tí afẹ́fẹ́ ti ń fẹ́ wá.
Dan 8:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí mo ṣe ń ronú nípa èyí, lójijì ni òbúkọ kan tí ó ní ìwo láàrín ojú u rẹ̀ méjèèjì jáde láti ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó la gbogbo ayé kọjá láìfi ara kan ilẹ̀. Ó tọ àgbò tí ó ni ìwo méjì náà wá, èyí tí mo rí tó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Ulai, ó sì dojúkọ ọ́ pẹ̀lú ìrunú tí ó lágbára. Mo rí i tí ó fi ìtara kọlu àgbò náà, ó lu àgbò náà bolẹ̀, ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì. Àgbò náà kò sì ní agbára láti dojúkọ ọ́, Òbúkọ náà kàn án mọ́lẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kò sì ṣí ẹni tí ó lè gba àgbò náà là kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀. Òbúkọ náà sì di alágbára púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé góńgó, agbára rẹ̀ ru sókè, ìwo ńlá a rẹ̀ sì ṣẹ́ dànù, ní ipò o rẹ̀, ìwo mẹ́rin mìíràn hù, ó sì yọrí sí ìhà igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.