Dan 6:25-28
Dan 6:25-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni Dariusi, ọba kọwe si gbogbo enia, orilẹ, ati ède ti o wà ni gbogbo aiye pe, Ki alafia ki o ma bi si i fun nyin. Mo paṣẹ pe, Ni gbogbo igberiko ijọba mi, ki awọn enia ki o ma warìri, ki nwọn si ma bẹ̀ru niwaju Ọlọrun Danieli, nitoripe on li Ọlọrun alãye, on si duro lailai, ati ijọba rẹ̀, eyi ti a kì yio le parun ni, ati agbara ijọba rẹ̀ yio si wà titi de opin. O ngbà ni, o si nyọ ni, o si nṣe iṣẹ-ami ati iṣẹ-iyanu li ọrun ati li aiye, ẹniti o gbà Danieli là lọwọ awọn kiniun. Bẹ̃ni Danieli yi si nṣe rere ni igba ijọba Dariusi, ati ni igba ijọba Kirusi, ara Persia.

Dan 6:25-28 Yoruba Bible (YCE)
Dariusi ọba bá kọ ìwé sí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà tí ó wà ní orí ilẹ̀ ayé ó ní, “Kí alaafia wà pẹlu yín, mo pàṣẹ pé ní gbogbo ìjọba mi, kí gbogbo eniyan máa wárìrì níwájú Ọlọrun Daniẹli, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ̀. “Nítorí òun ni Ọlọrun Alààyè tí ó wà títí ayérayé. Ìjọba rẹ̀ kò lè parun lae, àṣẹ rẹ̀ yóo sì máa wà títí dé òpin. Ó ń gbani là, ó ń dáni nídè. Ó ń ṣiṣẹ́ àánú tí ó yani lẹ́nu ní ọ̀run ati ní ayé. Òun ni ó gba Daniẹli lọ́wọ́ agbára kinniun.” Nǹkan sì ń dára fún Daniẹli ní àkókò Dariusi ati Kirusi, àwọn ọba Pasia.
Dan 6:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà, ni Dariusi ọba kọ̀wé sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti gbogbo jákèjádò ilẹ̀ náà: “Kí ìre yín máa pọ̀ sí i! “Mo gbé àṣẹ kan jáde wí pé: ní gbogbo agbègbè ìjọba mi, gbogbo ènìyàn gbọdọ̀ bẹ̀rù, kí wọn kí ó sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Daniẹli. “Nítorí òun ni Ọlọ́run alààyè Ó sì wà títí ayé; Ìjọba rẹ̀ kò le è parun ìjọba rẹ̀ kò ní ìpẹ̀kun Ó ń yọ ni, ó sì ń gbani là; ó ń ṣe iṣẹ́ ààmì àti ìyanu ní ọ̀run àti ní ayé. Òun ló gba Daniẹli là kúrò lọ́wọ́ agbára kìnnìún.” Daniẹli sì ṣe rere ní àkókò ìjọba Dariusi àti àkókò ìjọba Kirusi ti Persia.